Miliọnu lọna ogun naira lawọn ajinigbe to ji aburo aṣofin ipinlẹ Ọyọ gbe n beere fun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ipenija eto aabo ti ipinlẹ Ọyọ n koju lọwọlọwọ yii tun ti gbọna mi-in yọ bayii pẹlu bi wọn ṣe ji aburo ọkan ninu awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Tẹjumade Babalọla, gbe.

Obinrin naa ni aburo Ọnarebu Sunkanmi Babalọla ti i ṣe igbakeji awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju lọ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ. Adugbo Mọnatan, nigboro n’Ibadan ni wọn ti ji gbe.

Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lawọn ẹbi ti n wa obinrin naa nigba ti wọn ko ri i ko dari wale lati ibi to dagbere fun wọn pe oun n lọ. Nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni wọn too gba ipe abami kan, pe akata awọn ajinigbe lẹni ti wọn n wa wa.

Awọn ajinigbe wọnyi ko fi ọrọ sabẹ ahọn sọ, wọn ni bi idile Babalọla ba ni ẹmi ọkan ninu wọn yii i lo, miliọnu lọna ogun Naira (N20m) ni ki wọn yara lọọ tọju kiakia, bi bẹẹ kọ, pipa lawọn yoo pa ọmọbinrin naa danu sinu igbo.

Mọlẹbi Tẹjumade kan to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe akitiyan awọn lati bẹ awọn ajinigbe naa lati ana ọhun ko seso rere nitori ipe awọn ko wọle sori nọmba ti wọn fi pe awọn rara.

 

Akitiyan ALAROYE lati gbọ tẹnu awọn agbofinro lori iṣẹlẹ yii ko seso rere pẹlu bi akọroyin wa ṣe gbiyanju lati ba SP Olugbenga Fadeyi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọrọ lori foonu, ṣugbọn ti eyikeyii ninu awọn ipe rẹ ko seso rere titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply