Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn agbebọn to ji pasitọ ijọ Deeer Life gbe ninu sọọsi rẹ to wa niluu Irẹṣẹ, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, ti ni miliọnu lọna ọgbọn naira lawọn fẹẹ gba lọwọ awọn ẹbi rẹ ki awọn too le tu u silẹ ninu igbekun to wa.
Ọjọruu, Wẹsidee, lawọn ajinigbe ọhun kan sawọn ẹbi Pasitọ Ogedemgbe lori aago, ti wọn si n kilọ fun wọn pe owo ti awọn n beere fun naa ko gbọdọ din kọbọ ti wọn ba ṣi fẹẹ ri ẹni wọn ọhun pada laaye.
Iyawo olusọaguntan ọhun, Abilekọ Yinka Ogedemgbe, ti rọ ijọba atawọn ẹsọ alaabo lati wa gbogbo ọna ti wọn yoo fi gba ọkọ rẹ silẹ lọwọ awọn to ji i gbe.
O ni o lawọn oogun kan ti ọkọ oun maa n lo n i gbogbo igba latari ailera rẹ ati pe inu ewu nla ni ẹmi rẹ wa ti ko ba ti raaye lo awọn oogun ọhun lasiko to yẹ ko lo o.
Nigba to sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni awọn ti n gbe igbesẹ lori bi iranṣẹ Ọlọrun naa yoo ṣe di riri pada laipẹ rara.
O ni ọjọ ti iṣẹlẹ yii ti waye ni kọmiṣanna awọn ti pasẹ fawọn agbofinro kan lati tọpasẹ awọn agbebọn ọhun, ki wọn si wa gbogbo ọna ti wọn yoo fi gba pasitọ naa pada lọwọ wọn.