Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ kẹwaa, oṣu karun-un yii, ni olobo ta awọn ọlọpaa teṣan Sango, nipinlẹ Ogun, pe awọn gende meji yii, Abiọdun Ogundele; ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Ọpẹyẹmi Ọlatubọsun, ẹni ọdun mejilelogun, fibọn gba ọkada lọwọ ọlọkada kan nibudokọ Jọju, wọn si ti fẹsẹ fẹ ẹ. Ṣugbọn nibi ti wọn ti n sa lọ naa lọwọ ọlọpaa ti tẹ wọn, ni gbogbo ipa wọn ba pin.
Ikọ adigunjale ẹlẹni mẹta ni wọn, awọn meji yii lọwọ wulẹ tẹ ni. DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, to fi iṣẹlẹ naa to wa leti ṣalaye pe Adesọji David lorukọ ọlọkada ti wọn yọ ibọn si, ti wọn si gba ọkada Bajaj lọwọ ẹ.
Bi wọn ṣe ṣiṣẹ naa tan lawọn kan pe awọn ọlọpaa, nigba ti ori yoo si ta ko awọn meji yii, wọn ko ti i rin jinna tawọn ọlọpaa fi de.
Bi wọn ṣe ri ọlọpaa ni wọn gbe ere da si i, ti wọn n sa lọ. Ṣugbọn gbogbo ere wọn naa ko mu nnkan kan wa, awọn agbofinro ka wọn mọ kọna, wọn mu wọn ṣinkun ni. Afi ẹni kẹta wọn nikan lo raaye sa lọ ni tiẹ, wọn si loun naa yoo bọ sọwọ laipẹ, awọn ọlọpaa lawọn yoo wa a.
Ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn ti wọn ko ti i yin ati ẹyọ kan ti wọn ti yin, pẹlu ọkada ti wọn ja gba naa lawọn ọlọpaa gba lọwọ awọn meji yii, awọn ati gbogbo ẹru ẹsibiiti naa ni wọn ti ko lọ sẹka itọpinpin.