Faith Adebọla
Ẹgbẹ ọlọsin maaluu, Miyetti Allah Cattle Breeders Association (MACBAN), ti parọwa pe kijọba jawọ ninu fifofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba, eyi tawọn ijọba ipinlẹ kan gun le lasiko yii, aijẹ bẹẹ, niṣe lofin naa maa mu ki maaluu gbowo leri gọbọi, wọn ni owo maaluu kan maa to miliọnu meji naira tabi ju bẹẹ lọ, ti wọn ba fofin ọhun mulẹ.
Akọwe ẹgbẹ naa, ẹka ti ilẹ Yoruba, Mallam Maikudi Usman, lo ṣekilọ yii, nibi apero ita gbangba kan tawọn aṣofin ipinlẹ Eko ṣe ninu ọgba ile aṣofin ọhun to wa l’Alausa, Ikẹja, nipinlẹ Eko.
Apero naa waye lati mọ ero araalu lori abadofin ta ko fifi maaluu jẹko ni gbangba nipinlẹ Eko, eyi tawọn aṣofin naa ti ba iṣẹ jinna lori rẹ.
Usman ni loootọ lawọn o nifẹẹ si bi awọn darandaran kan ṣe n huwakiwa, nigba ti wọn ba lọọ fi maaluu jẹko loko oloko, ti wọn ba ire-oko jẹ, tabi ti wọn tun huwa ọdaran mi-in, o ni ọpọ awọn darandaran wọnyi ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn, ajoji onimaaluu ni ọpọ ninu wọn.
O ni ajọṣe to danmọran ti wa laarin awọn darandaran ọmọ ẹgbẹ MACBAN pẹlu awọn baalẹ ati ọba to laṣẹ awọn agbegbe tawọn ti n fi ẹran jẹko debii pe ko si wahala kankan mọ bayii.
O ni ti abadofin ‘ma fi maaluu jẹko ni gbangba’ yii ba dofin, owo nla lawọn maa maa na lati pese ounjẹ ati itọju fun awọn maaluu, boun si ṣe n wo o, afaimọ ni owo tawọn eeyan yoo maa ra maaluu kan ko ni i to miliọnu meji naira, tabi ko ju bẹẹ lọ, tori ọsin maaluu loju kan wọn lowo ju dida ẹran kiri lọ.
Yatọ siyẹn, Usman ni “Awọn eeyan wa o mọ nipa ọsin maaluu ninu ọgba, eyi to ti mọ wọn lara ni fifi ẹran jẹko kaakiri, boya ki ijọba fun wa laaye lati ṣẹṣẹ maa kọ awọn darandaran ni ọsin ti igbalode tẹẹ n sọ yii, tori a o mọ nipa ẹ tẹlẹ.
Ijọba tun ni lati pese ilẹ, owo ati awọn nnkan mi-in ta a maa nilo ti wọn o ba fẹ ka fi maaluu jẹko kaakiri.
Nipinlẹ Ondo, Ọyọ ati Ekiti, ti wọn tiẹ ni papa ijẹko to pọ ju ti Eko lọ, a ti ṣẹpade pẹlu awọn onilẹ ati awọn alaṣẹ ibẹ, ajọsọ ati agbọye si ti wa laarin wa, pẹlu adehun ti a jọ fẹnuko le lori.”
Ṣugbọn nigba to n fesi lori ọrọ yii, olori awọn aṣofin naa, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, ẹni ti Igbakeji rẹ, Ọnarebu Wasiu Ẹṣinlokun-Sanni, ṣoju fun sọ pe loootọ ni ọsin ẹran loju kan wọn lowo ju fifi ẹran jẹko ni gbangba lọ, ṣugbọn iwọnba ni inira ti ayipada naa yoo mu wa nibẹrẹ, to ba ya, awọn eeyan yoo janfaani ofin tuntun tawọn n po pọ lọwọ yii.
Ẹṣinlokun-Sanni ni “Se ẹ ranti pe tẹlẹtẹlẹ, gbangba tawọn eeyan n sin adiẹ, gbangba ni wọn n sin ẹlẹdẹ, ṣugbọn ni bayii, inu keeji (cage) ni wọn ti n sin wọn, ko si sẹni to tun n saroye lori owo ti wọn n ta awọn nnkan ọsin wọnyi mọ, tabi ki wọn tun da ọsin adiẹ ati ẹlẹdẹ pada soko aarọ ti wọn ti n sin wọn ni gbangba tẹlẹ. Bẹẹ ni ti maaluu yii naa maa ri to ba ya, o le kọkọ nira diẹ o, ṣugbọn irọrun lo maa ja si nigbẹyin.”