Mimu omi kanga lasiko omiyale yii lewu gidi o – Ijọba Ogun

Gbenga Amos, Ogun

Ijọba ipinlẹ Ogun ti ṣekilọ fawọn araalu lati yẹra fun mimu omi kanga, tabi omi kanga-dẹrọ ti wọn n pe ni borehole water lede oyinbo lasiko yii. Wọn ni ewu nla ati fifi ilera ẹni dẹjaa lo jẹ lasiko yii, tori iṣoro omiyale to gbode kan lawọn agbegbe kan nipinlẹ naa.

Kọmiṣanna to n mojuto ọrọ ayika nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ọla Ọrẹsanya, lo parọwa yii lọjọ Aiku, Sunday to lọ, lasiko to n ṣabẹwo sawọn agbegbe ti omiyale ti n han wọn leemọ lọna ati wa ojuutu siṣoro naa.

Lasiko abẹwo ọhun, Ọrẹsanya de awọn ilu to wa lẹnu aala ipinlẹ Ogun si Eko, bii Iṣẹri, Warewa, Magboro, Arepo ati bẹẹ bẹẹ lọ, pẹlu awọn ẹsiteeti oriṣiiriṣii to wa lagbegbe wọnyi.

O ni arọwa yii pọn dandan tori akunya omi to ṣẹlẹ lawọn agbegbe yii ti ṣakoba fun omi abẹlẹ to n ṣan kọja, ọpọ ẹgbin ati arun lo si ti sodo sinu omi naa, to mu ko lewu lati mu iru omi bẹẹ. Lara ohun to sọ mimu omi naa deewọ ni awọn oogun apakokoro oniruuru to ti rọ da sinu omiyale ọhun, ẹgbin ori akitan, irin to ti dipẹta, awọn saare oku ti ọgbara wẹ sita, koto ti wọn n ṣe igbọnsẹ si to kun akunfaya, awọn oku ẹran ati bẹẹ bẹẹ lọ. Gbogbo nnkan ẹgbin yii lo lawọn to ba mu omi kanga yoo kagbako rẹ, ti eyi si le kọle arun nla sagọọ ara wọn.

Bakan naa ni Kọmiṣanna ọhun ṣalaye pe ki i ṣe omi ti wọn ṣi silẹ ni Ọyan Dam to wa l’Abẹokuta lo ṣokunfa omiyale yii, o ni irọ lawọn to n sọ bẹẹ n pa, arọọda ojo ati awọn koto idaminu ti idọti di lo mu ki wahala omi naa pọ to bẹẹ lọdun yii, ṣugbọn gbogbo igbesẹ nijọba ipinlẹ Ogun ti n gbe lati daabo bo awọn araalu ati dukia lọwọ ofo ati adanu omiyale.

Leave a Reply