Faith Adebọla, Eko
Latari arọwa ti gomina pa sawọn ọdọ atawọn gbajumọ oṣere kan to darukọ pe ki wọn dara pọ mọ oun lati yan bii ologun loṣu Disẹmba yii, gẹgẹ bii ami fun alaafia lori ọrọ EndSARS to n da awuyewuye silẹ, gbajugbaja oṣere ati adẹrin-in poṣonu nni, Debọ Adedayọ, tawọn eeyan mọ si Mista Makaroni, ati ẹlẹgbẹ rẹ, onkọrin taka-sufee nni, Ọgbẹni Fọlarin Falana, ti inagijẹ rẹ n jẹ Falz ti lawọn o ni i yan bii ologun kankan pẹlu gomina rara, awọn o si ni i rin irin alaafia kan ni tawọn.
Ṣe, ninu ọrọ akanṣe kan to ba awọn olugbe ipinlẹ Eko sọ lori redio ati tẹlifiṣan lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Sanwo-Olu ti loun fi tifẹtifẹ ke sawọn ọdọ atawọn tọrọ iwọde EndSARS naa ka lara, lati jẹ kawọn bẹrẹ igbesẹ ọtun, lati wo ipinlẹ Eko san.
Sanwo-Olu ni: “Mo fi tifẹtifẹ ke si Ọgbẹni Fọlarin Falana, ti inagijẹ rẹ n jẹ Falz, Ọgbẹni Debọ Adedayọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Mista Makaroni, Ọgbẹni Dele Farotimi, Temitọpẹ Majẹkodunmi, Ṣegun Awosanya, tawọn eeyan mọ si Segalinks, Adetoun, Ṣeun Kuti, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, Ọga agba ikọ RRS, CSP Yinka Ẹgbẹyẹmi, pe ki wọn jẹ ka jọ rin irin alaafia lọ si Too-geeti Lẹkki, lọjọ naa. Ẹ darapọ mọ mi, ka jọ rin irin yii fun ipinlẹ wa ọwọn.”
Ṣugbọn, o fẹrẹ jẹ loju-ẹsẹ lawọn oṣere meji yii ti fesi pada fun Gomina Sanwo-Olu pe awọn o ni i kopa ninu irin alaafia rẹ ọhun. Ọtọọtọ lawọn mejeeji fi aidunnu wọn han.
Mista Makaroni sọ lori ikanni tuita rẹ pe: “Mo fi tọwọtọwọ kọ ipe gomina yii. Ijọba funra wọn ni wọn gbe igbimọ oluwadii dide. Igbimọ naa ti mu awọn aba ati amọran kan wa. Mo ro pe igbesẹ akọkọ lati wa alaafia ni kijọba bẹrẹ si i ṣiṣẹ lori awọn aba ati amọran wọnyẹn na, igba yẹn la ṣẹṣẹ le maa fojuure wo ijọba, igba yẹn la le maa fọkan tan wọn. Irin ti mo rin lọjọsi, ṣebi niṣe ni wọn gba mi mu, ti wọn sọ mi satimọle, ti wọn ja mi sihooho, wọn foju mi gbolẹ loriṣiiriṣii ọna. Bẹẹ mi o gbebọn, mi o si mu nnkan ija oloro kankan dani. Bi wọn ṣe n lu mi ni wọn bi mi leere pe kin ni mo jẹ yo ti mo n da gomina laamu. O waa ya tan, ẹ ni ka jọ maa yan kiri. Ṣe kẹ ẹ le tun raaye lu mi ni, mi o lọ ọ.
Ẹ jọọ, ti mo ba fẹẹ yan bii ologun lati din isanra mi ku, ma a lọ sibi ti wọn ti n ṣe iyẹn. Irin alaafia tawọn ọdọ Naijiria kan rin lọjọsi, ti wọn yinbọn pa wọn tori ẹ, awọn mi-in ṣi wa lẹwọn doni, awọn mi-in si ti lọọ fori wọn pamọ, ti wọn o le jaye ori wọn bo ṣe wu wọn, gbogbo ẹ ko si kọja pe wọn lawọn o fẹ iwakiwa tawọn ọlọpaa n hu lọ.”
Ni ti Falz to jẹ ọmọ gbajugbaja agbẹjọro nni, Amofin agba Fẹmi Falana, o ni: “Ọrọ nipa ‘irin alaafia’ ti wọn pe wa si yii da bii awada lasan leti mi, o tiẹ bu-uyan ku pẹlu. Wọn pa awọn ọmọ ọlọmọ nipa ika, ko si ti i si idajọ ododo kan lori ẹ lẹyin ọdun kan, bawo waa ni alaafia ṣe fẹẹ wa ti ko ba sidaajọ ododo?
‘‘Ninu ọrọ ti gomina sọ, wọn ni ki ilu too wa deedee, idajọ ododo gbọdọ wa nibẹ. Ẹ o ranti pe awọn ọdọ ọmọ Naijiria ni awọn ṣọja Naijiria fi ibọn da ẹmi wọn legbodo, ẹ fẹẹ dọgbọn daṣọ bo ọrọ lori, kẹ ẹ pa a mọlẹ. Ṣe bi ilu ṣe le wa deedee niyẹn.
Titi doni yii ṣi lawọn ọlọpaa n halẹ mọ awọn ọdọ Naijiria, ti wọn si n ṣe wọn baṣubaṣu lai yẹ, ẹ si dakẹ nipa ẹ, abi ẹ maa lẹ o mọ pe o ṣi n ṣẹlẹ bẹẹ ni? EndSARS.”
Fọlarin Falana lo kọ bẹẹ sori ikanni tuita (twitter) rẹ, bayii si loun ati Mista Makaroni lawọn o ni i rin irin alaafia kan pẹlu gomina lọjọ kẹfa, oṣu kejila yii.