Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Gospel Osuala, pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji, Ọladele Ibukun ati Dayọ Akinlade ni wọn ti wa ni ahamọ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan wọn.
Ninu alaye ti Alakooso ajọ naa nipinlẹ Ondo, Hammed Abọdunrin, ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n ṣafihan awọn afurasi ọhun ni olu ileesẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
O ni Gospel gan-an lo n ji awọn mita ọhun tu nibi tawọn onimita ba de e mọ niwaju ile wọn, ṣugbọn to jẹ pe iṣẹ ti Ibukun to to bii ọmọ ọdun mejilelogoji ati Dayọ, ẹni ogoji ọdun, yan laayo ni tiwọn ni ki wọn maa wa onibaara fun ọja ole ti olori wọn n ta.
Awọn mẹtẹẹta naa lo ni awọn ti ṣetan lati wọ lọ sile-ẹjọ lati lọọ foju wina ofin lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Gospel ninu ọrọ tirẹ ni mita mẹjọ loun ranti pe oun ti ji tu bo tilẹ jẹ pe mẹta pere lawọn ẹsọ alaabo ka mọ oun lọwọ, ti oun si ti lu marun-un yooku ta ni gbanjo.
O ni oun mọ pe oun ti daran, ṣugbọn kawọn sifu difẹnsi foriji oun, nitori pe oun ko deedee di gbewiri ọsan gangan, iya ajẹpalori pẹlu ebi ọgaja fọwọ mẹkẹ lo sun oun debẹ.