Faith Adebọla
Igbakeji aarẹ ilẹ wa nigba kan, Alaaji Atiku Abubakar, ti kede pe toun ba fi le dori aleefa gẹgẹ bii aarẹ orileede yii, awọn nnkan pataki marun-un kan wa toun maa ṣe, ṣugbọn oun maa ri i daju pe ọdọ lẹni toun maa fa ijọba le lọwọ toun ba kuro nipo naa.
Atiku ṣọrọ yii lasiko ayẹyẹ nla kan to waye ni gbọngan apero International Conference Center (ICC), niluu Abuja, nibi to ti kede fun gbogbo araalu nipa erongba rẹ lati jade dupo aarẹ lasiko idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023. Ẹgbẹ oṣelu PDP l’Atiku fẹẹ ba jade.
Ẹsẹ ko gbero ni gbọngan apero naa, nibi ti gomina ipinlẹ Adamawa, Alaaju Umaru Fintiri, to jẹ olugbalejo pataki, Sẹneto Dino Melaye lati ipinlẹ Kogi, pesẹ si, pẹlu ọgọọrọ awọn oloṣelu ati ololufẹ Atiku.
Ninu ọrọ rẹ, Atiku Abubakar ni koko marun-un toun maa ṣiṣẹ le lori toun ba di aarẹ ni bi Naijiria ṣe maa wa niṣọkan lodidi, bi eto aabo ṣe maa sunwọn si i, ọrọ aje to ta sansan, eto ẹkọ to jiire, ati bi awọn ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ ṣe maa tubọ lagbara labẹ ofin, ti wọn yoo si lo nnkan amuṣọrọ fun anfaani araalu si i.
“Gbogbo wa la mọ pe iya kan to n jẹ Naijiria lọwọlọwọ ni aisi olori to muna doko. Ko ti i si igba kan ti ajọṣe to so wa pọ bii orileede kan di yẹpẹrẹ bii tasiko yii ri. Orileede yii ti di ọkọ oju omi to fẹẹ doju de bayii, afi ka tete doola ẹ. Idi ree ti inu mi fi dun lati kede pe mo maa dupo aarẹ orileede Naijiria lọdun 2023, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), lagbara Ọlọrun. Mo fa ara mi kalẹ lati yọ ọkọ orileede wa to fẹẹ doju de yii, jade, ki n si tubọ gbe e lọ soju ọna to maa tọ de ebute ayọ, ebute idunnu.”
Bi Atiku ṣe n sọrọ yii, bẹẹ latẹwọ n ro waa waa. Gbogbo awọn to tun sọrọ lẹyin rẹ ni wọn gboṣuba fun ipinnu rẹ lati ṣiṣẹ fun orileede Naijiria, wọn loun lo to ẹru naa i gbe, wọn si ṣadura fun un.
Bi eto naa ṣe n lọ lede oyinbo ni wọn fọwọ tumọ rẹ si ede awọn aditi.
Tẹ o ba gbagbe, eyi ni igba karun-un ti Atiku Abubakar to ti figba kan wa nipo ọga agba ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa ri yoo jade dupo aarẹ, lẹyin ọdun mẹjọ to fi ṣe igbakeji aarẹ pẹlu Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣugbọn to n fidi rẹmi lẹnu igbiyanju rẹ.