Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Araba Awo tilẹ Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ti sọ pe ko si ohun to yẹ ko maa da wahala silẹ laarin awọn Kristiẹni ati Musulumi lori ọrọ lilo hijaabu to ba jẹ pe iha kọọkan wọn gbọ agbọye ẹsin, ti wọn si mọ pe ifẹ la fi i gbele aye.
Oloye Ẹlẹbuibọn ṣalaye ọrọ yii fun ALAROYE niluu Oṣogbo lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. O so pe, “Ko yẹ ki hijaabu le da wahala silẹ rara, mo ro pe agbọye ẹsin ati ifẹ ni ko si, ti a ba gbọ agbọye ẹsin daadaa, ṣe ti ẹni to wọ hijaabu ba jokoo ti ẹni ti ko wọ hijaabu, ṣe ina maa jo o lara ni abi o maa ko nnkan ran an?
“Ti eeyan ba fi rosary sọrun, ti ẹlomi-in si fi ilẹkẹ otutu-ọgbọ sọrun, ṣe o para wọn lara ni? Agbọye ẹsin ni ko si, ko si si ifẹ laarin awọn Kiriyo ati Musulumi, to ba jẹ pe loootọ iha ibi kan naa ni ẹsin mejeeji ti wa; ilẹ Arab ati ilẹ Isreali, ti itan wọn si jọ ara wọn, ko yẹ ki nnkan le maa ri bẹẹ.
“Ti awa ti a jẹ ẹlẹsin ibilẹ ba waa sọ pe a fẹẹ wọ nnkan tiwa nkọ, ki ni wọn fẹẹ ṣe nigba ti Musulumi ba wa n ba Kristiẹni ja?
Lori boya ki awọn ọmọ ẹlẹsin abalaye naa maa mura nilana ẹsin wọn lọ sileewe, Oloye Ifayẹmi sọ pe “Daadaa, mo fọwọ si i pe ki awọn ọmọ ẹlẹsin abalaye naa maa mura lọ sileewe nibaamu pẹlu ẹsin wọn.
“Ko le fa akọlukọgba kankan nibẹ, nigba ti ko pa ẹnikẹni lara, ki ni buruku to wa ninu ẹ? Ti o ba we gele, ti mo de fila, ki n waa sọ pe gele tiẹ n daamu fila mi. Ko si nnkan to para wọn lara nibẹ, ifẹ ni ko si, agbọye ẹsin ni ko si si”
Baba Ẹlẹbuibọn waa gba ijọba nimọran pe ‘Ki wọn gba onikaluku laaye lati ṣe ẹsin rẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ, ki wọn jẹ ki eleegun bọ eegun, ki oloro bọ oro rẹ, ko si eyi to pa ọkan lara nibẹ, lati maa fikan di ọkan lọwọ ko bojumu.
“Ko si ẹsin ti ko sunwọn, awọn eeyan ti n ṣe ẹsin ni wahala, gbogbo nnkan ti ko le rara ni wọn n mu ni lile koko.”