Mo maa fopin si owo tawọn agbero ati ọmọọta n gba l’Ekoo- Jandor

Monisọla Saka

Oludije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Abdulazeez Ọlajide Adediran, ti gbogbo eeyan mọ si Jandor, ti ṣeleri pe oun yoo jẹ ki awọn eeyan ipinlẹ Eko ni igbe aye ọtun, oun o si ni i gba kawọn janduku agbowo-ipa kan yan wọn jẹ mọ bi wọn ba le fibo gbe oun wọle gẹgẹ bii gomina lọdun 2023. O sọrọ yii lasiko tawọn eeyan ipinlẹ Akwa Ibom, ti wọn fi ipinlẹ Eko ṣe ibugbe n jẹjẹẹ atilẹyin fun ọkunrin naa ko le baa ṣe aṣeyọri ninu ibo ọdun to n bọ.

Lasiko to n sọrọ lọjọ Aiku, Sannde, nibi eto kan ti oludije dupo gomina lẹgbẹ PDP nipinlẹ Akwa Ibom, Pasitọ Umo Eno, ṣagbekalẹ rẹ, eyi to waye ni Nigerian Airforce, Kofo Abayọmi Street, agbegbe Victoria Island, l’Ekoo, lo sọ eleyii di mimọ.

Pẹlu igboya ni Jandor fi n sọ pe oun loun maa di gomina kẹrindinlogun nipinlẹ naa, ati gomina olominira to maa da duro lai ni baba isalẹ loun.

O ni, “A maa pese eto iṣejọba tuntun nipinlẹ Eko, a o si tọwọ iwakiwa ati ijẹkujẹ awọn agbero onimọto, awọn Iyalọja ati Babalọja bọlẹ. Ẹni to ba ṣadeede tilẹkun ọja pa l’Ekoo yoo ri ẹwọn he, mo si n sọ ọ ni gbangba pe emi o ni i ni baba isalẹ kankan ti ma a maa ba buruburu fun, ti yoo si maa paṣẹ bi mo ṣe fẹẹ ṣejọba fun mi, nipinlẹ ti mo n ṣe olori fun.

Bakan naa la tun maa ri i daju pe owo-ori tabi owokowo kan ti wọn ba n gba lọwọ awọn eeyan ipinlẹ yii, awọn naa la maa lo o fun, yatọ si bawọn ti wọn wa nibẹ lọwọlọwọ bayii ṣe n ṣe e. Akoko ti to bayii lati gba awọn eeyan kuro loko ẹru”.

Adediran tun ṣeleri fawọn ti ki i ṣe ẹya Yoruba ti wọn n gbe nipinlẹ naa pe ninu alaafia ati iṣọkan ni wọn yoo maa gbe labẹ iṣejọba oun. ati pe awọn yoo mọ riri ipa tawọn naa n ko ninu idagbasoke eto ọrọ aje ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso oun.

Leave a Reply