Mo mọ pe ara n ni yin o, amọ ẹ dibo fun Tinubu ki iṣakoso wa le tẹsiwaju-Buhari

 Faith Adebọla

Lai fi ti ọda owo, ọwọngogo epo bẹntiroolu, atawọn ipenija ọlọkan-o-jọkan to n koju awọn ọmọ orileede Naijiria lasiko yii pe, Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ wọn pe ki wọn tubọ ni amumọra, ki wọn ma si ṣe kaaarẹ ọkan, o ni adun ni i gbẹyin ewuro, ati pe oun gba wọn niyanju lati dibo fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ko baa le tẹsiwaju ninu iṣejọba rere tawọn ti n ba bọ, ko si mu un tẹsiwaju.

Ọrọ iyanju yii lo wa ninu iṣẹ pataki kan ti Buhari fi ṣọwọ sorileede yii lati orileede Ethiopia to wa lọwọlọwọ, eyi ti wọn tẹ jade, ti wọn si tun ṣe fidio ibi t’Aarẹ ti n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ. Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Garba Shehu, lo taari ọrọ naa sita.

Aarẹ Buhari ni:

Ẹyin ọmọ Naijiria ẹlẹgbẹ mi, mo fẹẹ fi anfaani yii dupẹ lọwọ yin lẹẹkan si i pe ẹ yan mi sipo aarẹ yin lẹẹmeji.

“Mi o si lara awọn oludije funpo oṣelu ninu ibo to n bọ yii, ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu mi, All Progressives Congress (APC), ti fa oludije kan kalẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Bi mo ṣe sọ tẹlẹ, Tinubu nigbagbọ ninu iṣọkan Naijiria, o nifẹẹ awọn eeyan ẹ, o si fẹ ki idagbasoke de ba Naijiria yii.

“Mo ke si gbogbo yin pe kẹ ẹ dibo fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, o ṣee fọkan tẹ, mo si nigbẹkẹle pe yoo ṣe alekun idagbasoke ti ijọba wa ni.

“Ni ipari, mo fẹẹ fi da yin loju pe gbogbo inira ati ipọnju tẹ ẹ n la kọja lasiko yii, latari awọn eto kan ta a gbe kalẹ ni mo mọ daadaa, bẹẹ ki nnkan le sunwọn si i lorileede yii la ṣe ṣe e.

“Mo rọ yin pe kẹ ẹ tubọ bomi suuru mu, a ti n gbe awọn igbesẹ lati mu adinku ba inira ati pakanleke yii. Lagbara Ọlọrun, didun lọsan yoo so nigbẹyin.”

Bẹẹ ni Buhari wi o.

Leave a Reply