Monisọla Saka
Ọmọkunrin kan to sọ ara rẹ di obinrin nipa mimura bii abo, to tun jẹ gbajumọ lori ẹrọ ayelujara nilẹ wa, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky, to n fi iṣesi, ihuwasi, irisi ati imura ṣe bii obinrin ti pariwo sita bayii, bẹẹ lo si n rawọ ẹbẹ sawọn eeyan, paapaa ju lọ awọn ololufẹ ẹ pe asiko ti to bayii foun naa lati di abiyamọ, ki wọn ba oun wa obinrin ara ilu oyinbo to le ba oun gbe oyun, ti yoo si ba oun bimọ naa nitori agba ni tara oun.
Bobrisky ni oun to n dun ni lo n pọ lọrọ ẹni, o bẹrẹ si i ka awọn dukia to ni ati ibi to ni ọpọlọpọ wọn si kalẹ, o ni ko ni i daa koun ku akurun bii iṣu, koun ma rẹni fẹyin silẹ fun tori iku o dọjọ, arun o doṣu.
O lọmọ obinrin lo wu oun koun kọkọ fi ṣe akọbi, o ni ti eyi ba ri bẹẹ, oun maa kẹ ọmọ naa debi to lapẹẹrẹ, oun ko si ni i fi i silẹ niṣẹẹju kan bayii. O loun n wa arẹwa obinrin lati orilẹ-ede Amẹrika tabi UK to le ba oun gbe oyun naa, ti yoo si ba oun bimọ oun nitori oun n wa ọmọ lọwọ yii gidigidi ni. O fi kun un pe ẹbun pataki ati ọpọlọpọ owo wa nilẹ fun obinrin to ba le ṣe oun ti oun n fẹ yii.
Ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn yii ni lọjọ toun ba di ọlọmọ, agaga ọmọ obinrin, lọjọ naa loun yoo pe lọọya oun ko waa kọ wíìlì gbogbo ogun oun fọmọ naa, tori oun n wa ẹni to maa jẹ gbogbo ogun toun ni silẹ rẹkẹrẹkẹ yẹn ni.
Nigba to n ka awọn ibi to ni dukia si, Bobrisky loun nile kan ni Bera Estate, ẹyọ kan ni Orchid road, ikan ni Pinnock, ileepo kan to ku diẹ koun pari ẹ lagbegbe Lẹkki ati otẹẹli kan ni Lẹkki kan naa, atawọn mi-in toun ko fẹẹ darukọ wọn.
Gẹgẹ bo ṣe kọ ọ sori ayelujara Snapchat ẹ, Bobrisky ni, “Latọdun to lọ lọhun-un nironu ọmọ bibi ti gba ọkan mi kan, mo si n fẹ ki akọbi mi wa lobinrin. Gbogbo aye mi ati nnkan ti mo ni ni ma a fi kẹ ẹ bajẹ. Lọjọ to ba dele aye ni ma a pe lọọya mi ko waa kọ iwe ipingun mi tori mo fẹran ọmọbinrin gidi gan-an ni, inu mi aa dun to ba le jẹ obinrin, tori wahala ọmọkunrin aa ti pọ ju, yoo si fi ibeere yi mi lori.
Mo ni dukia to pọ jaburata, mo si n wa ọmọ ti mo le fi gbogbo ẹ silẹ fun. Nigba ti ko sẹni to mọgba tiku le wọle de, ti n ba fi le bimọ obinrin pẹrẹn, Ọlọrun mi o, mi o ni fi i silẹ nigba kan. Ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ni mi bayii, ọjọ si n lọ niyẹn”.
Pupọ awọn eeyan ori ẹrọ ayelujara ni wọn ti n fi Bobrisky ṣe yẹyẹ ti wọn n sọko ọrọ si i lẹyin to bẹ awọn ololufẹ ẹ lati ba a wa obinrin to le ba a ru oyun ọmọ ẹ, ko bi i, ko si gbe nnkan oun le oun lọwọ.
Wọn ni ṣebi obinrin lo pe ara ẹ, ko wa ọkunrin to maa fun un loyun ti yoo si sanwo iṣẹ ẹ fun un to ba mọ pe oun fẹẹ ṣabiyamọ. Bẹẹ lawọn mi-in n bi i leere pe ṣe baba ọmọ yẹn ni Bobrisky yoo di ni abi iya, wọn ni ki lo de toun funra ẹ o le gbe oyun ọmọ ẹ sinu nigba to jẹ obinrin loun naa.
Awọn kan tilẹ ni ki Bobrisky ma fọrọ sabẹ ahọn sọ, wọn ni ko jẹwọ ara ẹ, ko sọ idi to fi jẹ pe ọmọ obinrin gangan lo n wa.