Wọti mu an ninu awọn Fulani to n jiiyan gbe ni Kaara

Gbenga Amos, Ogun

Adura ‘arinna-kore, akoya-ibi’ lawọn ero meje to wọkọ ayọkẹlẹ Ford kan gba, nigba ti wọn gbera irin-ajo wọn latilu Ilọrin si Eko, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an ta a wa yii, laimọ pe ibi ti lugọ de wọn lọna, awọn ajinigbe kọ lu ọkọ wọn bo ṣe ku diẹ ki wọn wọ Eko, wọn si ji ọkan lara awọn ero ọkọ naa gbe. Agbegbe biriiji Kara, to wa lọna marosẹ Eko s’Ibadan, nitosi ẹnu aala ipinlẹ Ogun ati Eko ni wọn ti ji wọn gbe, ṣugbọn ọwọ ti tẹ ọkan ninu awọn ajinigbe naa, Ọgbẹni Ibraheem Abubakar.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lori iṣẹlẹ ọhun pe dẹrẹba ọkọ ero ọhun ti nọmba rẹ jẹ LRN 596 ZY lo sare janna-janna de ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Warewa, nipinlẹ Ogun, pe ki wọn gba oun, o loun pẹlu awọn ero ọkọ toun n gbe bọ lati ilu Ilọrin lawọn jọ de ori biriiji Kaara yii, ibẹ lawọn ti kan gosiloo rẹpẹtẹ, lawọn ba ya bara si ọna abuja eruku to wa lẹgbẹẹ afara naa, bo ti lẹ jẹ pe koto-gegele gbagun-gbagun lọna naa ri, pẹlu ireti pe awọn yoo ti bu sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ sẹyin.

Awakọ naa sọ pe nibi toun ti n pẹwọ fun koto kan, ojiji lawọn afurasi ajinigbe bii marun-un yọ sawọn, wọn ṣuru bo ọkọ oun pẹlu nnkan ija oloro ti wọn gbe dani, lawọn ero ọkọ naa ba rọ jade, kaluku bẹrẹ si i sa asala fẹmi-in ẹ, bẹẹ loun naa n wa ọkọ ọhun pẹlu ojora niṣo.

O ni nigba toun fi maa duro niwaju, tawọn ero naa yoo fi ṣara jọ pada, ẹni meje ti ku mẹfa, awọn ajinigbe naa ti ji ọkan lara wọn, Alaaji Shehu Anafi, gbe. Adugbo Okeleelẹ, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ni wọn l’Alaaji ẹni ọdun mejilelọgọta (62) naa ti wa.

Oju-ẹsẹ ni DPO teṣan Warewa atawọn ọmọọṣẹ rẹ ti ta mọra, wọn lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, wọn wọnu igbo tọ awọn ajinigbe ọhun lọ, wọn si jọ fija pẹẹta ni ibuba wọn.

Nigbẹyin, ọwọ tẹ ọkan ninu awọn ajinigbe to ṣiṣẹẹbi ọhun, awọn yooku ṣiyan, wọn ko duro gbọbẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ ninu wọn lo fara kaaṣa ọta ibọn awọn ọlọpaa, wọn si tun ri Alaaji Sheu naa gba silẹ lai fara pa.

Afurasi ajinigbe tọwọ ba yii ti jẹwọ ni teṣan ọlọpaa pe ọna Sabonganmu si Bompai, nipinlẹ Kano, l’Oke-Ọya, loun ti wa, o lara ikọ ẹlẹni meje to n ṣiṣẹ ajinigbe layiika biriiji Kaara loun, ṣugbọn ko ti i pẹ pupọ tawọn bẹrẹ ọpureṣọn awọn lagbegbe naa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Abiọdun Alabi, ti paṣẹ pe ki wọn taari afurasi ọdaran yii si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ to n gbogun ti iwa ijinigbe lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fun iwadii to lọọrin, bẹẹ ni iṣẹ ṣi n lọ lati ri awọn ajinigbe to sa lọ mu.

Leave a Reply