Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti fi igboya ṣalaye pe oun ṣi ni ireti ati igbagbọ pe Naijiria yii yoo ṣi dara ju bayii lọ, nitori ọna ta a le gba ṣẹgun iṣoro ta a ni pọ ju awọn iṣoro naa funra wọn lọ.
O sọrọ yii lasiko ayẹyẹ ọdun kọkanlelọgọta Ominiria Naijiiria ni ‘June 12’ Cultural Centre, Kutọ, Abẹokuta.
Gomina ṣalaye pe o ṣe pataki kawọn eeyan Naijiria pawọ-pọ lati koju awọn nnkan to n dena dide ilẹ ileri wa. O ni ijọba naa yoo ni lati ṣe ojuṣe tiẹ, awọn eeyan ilu naa yoo si nigbagbọ pe bayii kọ ni yoo maa ri lọ.
Dapọ Abiọdun tẹsiwaju pe loootọ ni Naijiria ko si ninu awọn alagbara agbaye, ṣugbọn bẹẹ naa kọ lo buru fun ilu yii to, aaye ọpẹ ṣi yọ.
Nipa ti ipinlẹ Ogun, Abiọdun ṣalaye pe ipinlẹ yii n ṣe ojuṣe rẹ lẹka ọrọ-aje Naijiria. O ni ipinlẹ yii ni akọkọ nipa pipese ohun idagbasoke ọrọ aje.
Gomina ko ṣai sọ nipa awọn iṣoro to n koju orileede yii, o ni ayẹyẹ Ominira bii eyi naa lo yẹ ka lo lati fi yanju ẹ, ki Naijiria, iru eyi ti kaluku n fẹ, le wa si imuṣẹ.
Bakan naa lo mẹnu ba ọrọ Korona, Abiọdun sọ pe pẹlu ifọwọsowọpọ, ogun aisan naa ti n ṣẹ diẹdiẹ. Ikọlu rẹ lori ọrọ aje naa si ti n dinku jọjọ.