Mo ti pin ogun mi lọdun to kọja, nigba ti dokita ni aisan to n ṣe mi ko gboogun- Kẹmi Afọlabi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Nnkan n ṣẹlẹ niju, wọn o gbọ letile, iyẹn lọrọ oṣere tiata to gbajumọ daadaa nni, Kẹmi Afọlabi, ẹni to kede rẹ lọjọ ọdun tuntun pe oun ko mọ pe oun yoo di asiko yii, oun tilẹ ti pin ogun oun lọdun 2021, nitori aisan to n ṣe oun ko gboogun rara.

Aisan kan ti wọn n pe ni SLE, iyẹn ‘Systemic Lupus Erythematosus’ lo n ṣe Kẹmi. Aisan naa ki i jẹ keeyan le mi daadaa ni, o lagbara pupọ, wọn si ni ko si oogun fun un.

Kinni naa lo tun kọ lu obinrin yii lọdun to kọja yii, to bẹẹ to jẹ ọjọ meji-meji lo n ṣayẹwo Korona, pe boya Korona lo n daamu oun. Bayii ni Kẹmi ṣe ṣalaye aisan rẹ naa.

“Mo kọ iwe ipingun mi, mo si ni ki wọn ba mi  faaye silẹ nileeṣẹ agbokuu Ebony Vaults, ṣugbọn Ọlọrun fi otitọ rẹ han mi lai wo ti ẹṣẹ mi. Ta ni mi t’Ọlọrun fi ka iwalaaye mi kun bayii???? Wọn n gbe mi lati ileewosan aladaani mi lọ LASUTH, nibi ti mo ti lo ju oṣu mẹta lọ.

“Nigbẹyin, wọn ri ohun to n ṣe mi, wọn ni ko gboogun (SLE) Omi di ẹdọforo mi, ko jẹ ki ọkan mi le ṣiṣẹ daadaa, ko jẹ ki n le mi daadaa. Iṣẹ abẹ nikan ni wọn le fi tu omi to di ẹdọforo mi ko kuro nibẹ. Odidi oṣu kan ni mo fi gba afẹfẹ eemi ( Oxygen) oun ni mo fi n mi. Igbesi aye mi ti yipada titi aye, ṣugbọn mo dupẹ pe mo ṣi n mi.”

Kẹmi ko ti i dakẹ,o tẹsiwaju pe iṣẹ tiata toun n ṣe naa wa nibẹ, o di dandan kawọn eeyan maa ri oun. Bi wọn ba ti ri oun toun tobi si i ni wọn yoo ti maa sọrọ pe ki lo ṣẹlẹ toun tun tobi bii eyi, bẹẹ wọn ko mọ pe oogun toun n lo lati ṣẹgun irora SLE lo n fa a toun fi n tobi.

Tẹ o ba gbagbe, niṣe lobinrin yii daku rangbọndan ni Saudi Arabia lọdun 2019, nigba to lọọ ṣiṣẹ Hajji, to jẹ ileeowsan lo laju si, aarẹ naa lo tun tẹsiwaju titi di 2021 to pari yii, ti Kẹmi fi ni lori ohun gbogbo ṣa, oun dupẹ pe ẹmi oun ṣi wa, oun ko ba ọdun naa lọ.

Nipa aisan SLE yii, awọn dokita sọ pe eeyan le jogun ẹ lara awọn to bi i, o le ṣẹlẹ siiyan lati ara ayika teeyan ba wa.

Nipa ohun ti yoo maa ṣẹlẹ seni to ba ni in, wọn ni tọhun ko ni i le mi daadaa, yoo maa rẹ ẹ lọpọ igba, o ṣee ṣe ki ara rẹ maa wu, bẹẹ ni tọhun yoo maa ni iṣoro ara riro.

Wọn lo tun ṣee ṣe ki tọhun ni aisan ọkan, aisan ẹdọforo, aisan kidinrin, giiri, awọka ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi ko ṣe waa gboogun to, wọn lo ṣee ṣe kẹni to ba n ṣe gbele aye pẹ, to ba n ri amojuto latọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa rẹ, ti ko si kọja aye rẹ, to n ṣọ iru aye to n gbe.

Leave a Reply