Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Mọto ibi ti wọn n lọ ni wọn fẹẹ wọ ti wọn fi duro lẹgbẹẹ titi, iyẹn awọn eeyan mẹwaa kan ti wọn duro lagbegbe Kudigbe, nitosi Arigbajo, loju ọna marosẹ Eko si Abẹokuta, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹsan-an yii, afi bi mọto Sienna kan ṣe lọọ kọ lu wọn, to si pa ọmọde ati iya arugbo kan.
Yatọ sawọn meji to ku yii, eeyan meje mi-in fara pa ninu awọn mẹwaa naa, ẹni kan ṣoṣo lori ko yọ ti nnkan kan ko ṣe.
Gẹgẹ bi Babatunde Akinbiyi, Alukoro TRACE nipinlẹ Ogun ṣe ṣalaye, o ni mọto Sienna ti nọmba ẹ jẹ KRD 900 GV, lo n sare buruku bọ ni nnkan bii aago meje aabọ kọja iṣẹju meji, laaarọ.
Nibi to ti n pẹwọ fun koto to wa lọọọkan lo ti padanu ijanu ẹ, lo ba kọ lu awọn ẹni ẹlẹni to duro lẹgbẹẹ ọna, ti wọn n wa mọto ti yoo gbe wọn lọ sibi ti kaluku wọn n lọ.
Nibẹ ni ọmọde kan to duro ti iya rẹ ti dagbere faye, ti iya agba to wa nitosi ọmọ naa si di oku pẹlu.
Bi mọto Sienna yii ṣe kọ lu wọn naa lo tun kọ lu mọto ayẹkẹlẹ Fọọdu kan ti nọmba ẹ jẹ AAB 439 XB, ati kẹkẹ Marwa ti nọmba tiẹ jẹ AKM 791 VP.
Mọṣuari to wa ninu Ọsibitu Jẹnẹra Ifọ ni wọn ko awọn oku mejeeji lọ, ọsibitu naa ni wọn si ko awọn meje to fara pa lọ pẹlu. Ọwọ ba dẹrẹba Sienna naa gẹgẹ bi Alukoro TRACE ṣe wi, wọn si ti gbe e lọ si teṣan ọlọpaa Itori pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ ati kẹkẹ Marwa ti ijamba kan naa.
Ọga TRACE, Kọmandanti Ṣeni Ogunyẹmi, rọ awọn ti wọn ba fẹẹ wọkọ lati maa duro ni awọn aaye ti wọn ya sọtọ gẹgẹ bii ibudokọ, ki wọn ma kan maa duro lẹgbẹẹ ọna, nitori awọn oniwakuwa dẹrẹba bii eyi.
Bakan naa lo rọ awọn to n patẹ ọja lẹgbẹẹ titi pe ki wọn yee ṣe bẹẹ, nitori iku ojiji bii eyi to rọ mọ ọn.