Monisọla Saka
Agbẹjọro kan to filu Abuja ṣe ibugbe, Osigwe Momoh, ti wọ ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije dupo aarẹ lẹgbẹ wọn, Bọla Ahmed Tinubu, lọ sile-ẹjọ giga ilu Abuja nitori Musulumi bii tiẹ to fa kalẹ fun igbakeji.
Lọọya yii rọ ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, lati fofin de ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC fa kalẹ lati dupo aarẹ, ki wọn ma si ṣe faaye gba wọn lati kopa lasiko ibo apapọ ọdun to n bọ, nitori ofin ilẹ yii to tẹ loju mọlẹ.
Ninu ọrọ rẹ lasiko to n fa ẹri yọ ninu iwe ofin orilẹ-ede yii lo ti ni, “Gẹgẹ bi iwe ofin ilẹ Naijiria ọdun 1999 ṣe wi, gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo gbọdọ tẹle ofin mimu aarẹ ati igbakeji rẹ lati inu ẹsin ati ẹya ọtọọtọ lorilẹ-ede yii.
Ofin yii ni Tinubu to jẹ oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC lu pẹlu Shettima to yan gẹgẹ bii igbakeji”.
Ajafẹtọọ-ọmọniyan yii waa rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ lati paṣẹ fun ajọ INEC lati ma ṣe gbe orukọ ẹni to n dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC jade fun ibo gbogboogbo ọdun 2023.
Ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu ati ajọ INEC ni olujẹjọ.
Wọn ko ti i fi ọjọ igbẹjọ lede.