Mutiat Adio tun rẹwọn he lẹyin to ti ṣẹwọn lẹẹmeji

Ẹwọn ọdun mẹta ni wọn tun sọ obinrin kan, Mutiat Adio, ti ile-ẹjọ ti kọkọ sọ sẹwọn lẹẹmeji ọtọọtọ lori oriṣiiriṣii ẹsun ọdaran si.

Ẹsun ti wọn fi kan an bayii ni pe o fi iwe sọwe-dowo san miliọnu kan aabọ naira (N1.5m), gẹgẹ biii owo mọto to ra lọwọ Fabunmi Samuel, ṣugbọn ti ko sowo ninu akaunti rẹ.

Wọn ni fun nnkan bii oṣu mẹta ni ko fi si owo ninu akaunti ti obinrin yii fun wọn ni iwe sọwe-dowo ẹ yii, bẹẹ igbakeji akọwe agba tẹlẹ ni nile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ọyọ.

Ninu ẹsun ti ajọ EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, to fi ilu Ibadan ṣebujokoo fi kan an ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ti dajọ obinrin yii lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

Agbẹnusọ fun ajọ naa, Ọgbẹni Wilson Uwujaren, sọ pe ki wọn too gbe idajọ kalẹ lo ti kọkọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ pe o fi ọgbọn gba owo, o tun fun eeyan ni iwe sọwe-dowo, bẹẹ ni ko si owo ninu akaunti rẹ.

Sugbọn lẹyin ti Adio jẹwọ pe oun jẹbi ni wọn sọ ọ sẹwọn ọdun mẹta, bakan naa ni Adajọ Owolabi paṣẹ pe ko san idaji miliọnu naira yooku fun ileeṣẹ Fatai Olanrewaju Motors, to ra mọto Toyota Pathfinder (2000) lọwọ wọn.

Ọgbọnjọ, oṣu kin-in-ni, ọdun 2018, ni wọn kọkọ gbe e wa sile-ẹjọ, nibi to ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ yii, ko too yi ọrọ ẹ pada pe loootọ loun jẹbi.

Adajọ Owolabi ti sọ pe ko lọọ ṣẹwọn ọdun mẹta, ko si tun da idaji miliuọnu pada fawọn to ra mọto lọwọ wọn, to fun ni sọwedowo ọhun.

Ni bayii, wọn lo ti digba mẹta ọtọọtọ ti ile-ẹjọ yoo ran Arabinrin Mutiat Adio yii lẹwọn.

Ọdun 2018 ni wọn kọkọ sọ ọ sẹwọn ọdun meje lori ẹsun pe o fọgbọn gba owo miliọnu mẹsan ati ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ ẹnikan to n jẹ Abiọdun Ọlọnade, tiyẹn n gbe lorilẹ-ede Ireland lọhun-un.

Lọjọ kẹfa oṣu kẹta ọdun 2020 ni wọn tun ran an lẹwọn ọdun marun-un lori ẹsun pe o ji owo to le ni miliọnu mejilelogun (N22,375,913) ni banki Guaranty Trust Bank Plc.

 

 

 

Leave a Reply