N ko da ẹgbẹ oṣelu kankan silẹ nitori ibo 2023 o – Ọbasanjọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọrọ gbogbo ki i se lori alabahun ni ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ. Baba naa wa lorilẹ-ede Afghanistan lọwọlọwọ, iroyin si n lọ nipa rẹ pe o ti da ẹgbẹ oṣelu tuntun silẹ ni Naijiria, o si ti yan awọn gomina atijọ mẹta bii oludari!

Iwe iroyin ede oyinbo kan lo gbe iroyin yii jade, ko si pẹ to fi tan kalẹ pe Ọbasanjọ ti bẹrẹ eto fun ibo 2023. Ọbasanjọ funra ẹ ri iroyin naa nibi to wa, ẹsẹkẹsẹ lo si ti fi iṣẹ naa le akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi, lọwọ, niyẹn ba sare gbe atẹjade sita laarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu keje yii, o ni ọga oun ko da ẹgbẹ oṣelu silẹ o.

Koda, iwe iroyin naa tun sọ pe ọjọ kẹtala, oṣu keje yii, ni Ọbasanjọ atawọn gomina atijọ naa yoo ṣepade lori ẹgbẹ oṣelu ti wọn n pete ẹ naa.

Nigba to n ṣalaye pe ko sohun to jọ bẹẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọ pe irọ gbuu ni iroyin ti ọkunrin Soni Daniel to kọ iroyin naa kọ nipa oun. O ni lasiko yii tabi laipẹ ọjọ, oun ko ni i lero lati da ẹgbẹ oṣelu kankan silẹ.

Ọbasanjọ sọ pe, “Lapa ibi ti mo ti wa lorilẹ aye, to o ba sọ pe o daarọ nibi kan, a ki i tun pada lọ sibẹ lọọ ṣe ‘ẹ kaalẹ mọ’. Ẹni to kọ iroyin ofege naa le ni lati kan si wọn ni Yaba apa osi, awọn to ba si n gba iru ẹ gbọ naa le tun gbagbọ pe ọkunrin niya awọn.

“Mo ti fi jijẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan silẹ tipẹ, ṣugbọn nitori ipo mi ni Naijiria, ati nilẹ Adulawọ, ni mo ṣe gbọdọ faaye silẹ fawọn eeyan to ba fẹẹ gba amọran lẹnu mi’’

Ẹgbẹ oṣelu Ọbasanjọ lasiko yii gẹgẹ bo ṣe wi ni tawọn ọmọ Naijiria to n koju iṣoro aabo, airiṣẹ-ṣe, ebi, oṣi ati oriṣiiriṣii iṣoro. O ni ẹgbẹ ta a gbọdọ ṣe niyẹn lati ṣẹgun awọn iṣoro wọnyi.

Ọbasanjọ ni kawọn to fẹẹ gbọna ẹyin fa oun wọ ẹgbẹ oṣelu pẹlu ipa tete mọ pe oun ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan mọ, amọran lo ku toun yoo maa gba awọn to ba wa nibẹ ni Naijiria, l’Afrika ati kari aye gbogbo

Leave a Reply