Faith Adebọla, Eko
Ogbontarigi onkọwe to dantọ ni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti sọ pe ko si ireti fun iṣọkan orileede yii labẹ ijọba Mohammadu Buhari to wa lode yii, tori gbogbo anfaani to le mu ka wa niṣọkan la ti sọnu.
Ṣoyinka ni bii igba teeyan n yin agbado sẹyin igba ni tẹnikan ba n sọrọ nipa iṣọkan labẹ iṣakoso Buhari yii, pẹlu ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ lorileede yii, niṣe ni Naijiria tubọ n sun mọ ikorita ipinya ati ituka ju wiwa niṣọkan lọ. O loun o si ti i ri ẹni to le da iṣọkan pada sorileede yii lọjọ iwaju.
Ilu Abuja ni Purofẹsọ naa ti sọrọ ọhun nibi ayẹyẹ afihan awọn iwe meji kan to ṣẹṣẹ kọ to pe akọle rẹ ni Chronicles of the Happiest People on Earth, ati ekeji, Trumpism in Academe, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii.
Gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha, lo bi Ṣoyinka leere pe ṣe o ṣi le kọ iwe kan to maa ṣakopọ gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria, to si maa mu kawọn eeyan nifẹẹ Naijiria, ki wọn si wa niṣokan.
Nigba to n dahun ibeere naa, Ṣoyinka ni: “Ki n ma purọ, nibi ti ọrọ orileede yii ba mi lọkan jẹ de, mi o ki i ka awọn iweeroyin ojoojumọ ilẹ wa mọ, tori awọn iroyin to maa n kun oju iwe akọkọ wọn le mu mu keeyan sorikọ, ki tọhun si di alaaarẹ. Awọn iroyin buruku, iṣẹlẹ gbankọgbi ati ajalu loriṣiiriṣii lojoojumọ ni.
“Bawo ni iṣọkan ṣe fẹẹ wa pẹlu awọn iṣẹlẹ wọnyi, orileede yii ti feeli, emi o gbagbọ pe iṣọkan le waye labẹ ijọba to wa lode yii.
“A lawọn asiko to yẹ ka ti tubọ mu korileede yii wa niṣọkan, ṣugbọn a sọ anfaani naa nu. Ni bayii, ẹmi iṣọkan, ironu iṣọkan ati isapa lati wa niṣọkan ko si ninu ọpọ eeyan mọ.
“Fun apẹẹrẹ, ko le sohun meji to maa wa lọkan awọn eeyan to kun ibudo ogun-le-n-de ti wọn wa kaakiri apa Oke-Ọya ju ki wọn ri ẹni gbẹsan wọn lara awọn agbebọnrin to sọ wọn di alainilelori lọ, ọrọ mi-in o le wọ wọn leti ju ki wọn ri idajọ ododo gba lọ. Bẹẹ orileede yii o le ni iṣọkan, ka sootọ, ti ko ba si idajọ ododo ati itanran.”
Ṣoyinka ni, gẹgẹ bii ẹnikan, ko wu oun pe ki orileede yii fọ si wẹwẹ, ṣugbọn ni idakeji, o lodi si ofin ijọba lati maa sọ pe isọkan orileede yii ki i ṣe ohun ta a le dunaa dura ẹ, o ni iṣọkan ki i ṣe tipatipa loju ohun to n ṣẹlẹ yii o.