Nbi ti wọn ti n le adigunjale, sifu difẹnsi yinbọn pa iyaale ile kan lasiko to fẹẹ kirun Yidi

 Adewale Adeoye

Nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lasiko tawọn ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi ‘Nigeria Security And Civil Defense Corps’ (NSCDC) ẹka tilu Gusau, nipinlẹ Zamfara, n le adigunjale kan lọ, ti wọn ṣeeṣi yinbọn fun iyaale ile kan lasiko to fẹẹ kirun Yidi fun ti ọdun Ramadan yii.

ALAROYE gbọ pe ṣe ni awọn ẹṣọ alaabo ọhun n le adigunjale kan to ni ohun ija oloro lọwọ lọ, bi wọn ṣe n le e lọ, bẹẹ ni wọn n yinbọn soke gbaugbau lati fi dẹruba a boya aa jẹ duro, ṣugbọn ṣe ni adigunjale ọhun n sa lọ lẹlẹẹlẹ, ko duro rara. Ọkan lara awọn ọta ibọn ti wọn yin lọjọ naa lo ṣeeṣi ba iyaale ile ọhun, to si ku loju-ẹsẹ, iṣẹlẹ ọhun lo mu ki idarudapọ  waye ni gbọngan ti wọn ti fẹẹ kirun naa.

Iṣẹlẹ ọhun lo mu kawọn araalu kina bọ ọkan lara awọn mọto tawọn sifu difẹnsi ọhun gbe wa sibẹ lọjọ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, A.S.P Yasid Abubarkar, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn ti fọwọ ofin mu meji lara awọn oṣiṣẹ ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ju sahaamọ awọn bayii.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹle ọhun lọ bayii pe, ‘‘Iwadii n lọ lọwọ nipa iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn ọlọpaa ti fọwọ ofin mu meji lara awọn oṣiṣẹ sifu difẹẹnsi ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun ju sahaamọ awọn ọlọpaa agbegbe naa bayii.

A n ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun lọwọ, ta a si maa jabọ iwadii wa fawọn araalu lẹyin ta a ba pari iwadii wa tan.

Ṣa o, Alukoro ajọ ọhun nipinlẹ naa, Ọgbẹni Ikor Oche, ni ko soootọ nipa ẹsun ti wọn fi kan oṣiṣẹ awọn yii rara.

O ni, ‘‘Loootọ ni awọn ẹṣọ sifu difẹnsi, ẹka agbegbe Gusau, nipinlẹ Zamfara, lọọ daabo bo awọn olujọsin ti wọn fẹẹ kirun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, wọn gburoo ibọn nibi ti wọn wa, wọn pe ara wọn jọ lati lọọ wo nnkan to n ṣẹlẹ, nigba ti wọn maa debẹ, oku iyaale ile kan ni wọn ba nilẹ to ti ku. Nitori pe awọn oṣiṣẹ ọhun lo wa nitosi lo mu ki awọn araalu fi ro pe awọn lo yinbọn lu iyaale ile naa, ni wọn ba bẹrẹ si i ba wọn fa wahala lọjọ naa. Wọn kina bọ awọn mọto wa lori iṣẹlẹ ọhun, sugbọn awọn ọlọpaa agbegbe naa ti pẹtu sọkan awọn araalu ọhun, ti gbogbo nnkan si ti pada si bo ṣe wa tẹlẹ bayii’’.

 

Leave a Reply