NDLEA ka Baalẹ mọ’nu oko igbo rẹpẹtẹ to gbin l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Orin ọkunrin onifuji nni, Abass Obesere, to kọ pe ‘ẹ lẹ o feṣu labule, baale n ta igbo, iyawo rẹ n ta ogogoro, ọmọ n gbowo ita, ti ṣẹ mọ Baalẹ kan, Akinọla Adebayọ, lara. Afaimọ kohun to ju eṣu lọ ma ti wọn abule rẹ bayii pẹlu bi ọwọ ajọ to n gbogun ti tita ati lilo oogun oloro lorilẹ-ede yii (NDLEA), ṣe tẹ ẹ ninu oko igbo rẹpẹtẹ to gbin sagbegbe Kajọla, eyi to wa ni aala ipinlẹ Ondo ati Edo. Ṣugbọn niṣe ni ajọ to n gbogun ti oogun oloro naa dana sun oko igbo to fẹrẹ to ogoji sare ọhun, ti wọn si tun fi panpẹ ofin mu baalẹ atawọn ọmọọṣẹ rẹ meji, Arikuyẹri ati Habib.

Agbẹnusọ fun ajọ naa, Fẹmi Babafẹmi, lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu yii.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta yii, lawọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA ya wọnu oko igbo naa, wọn si ba Baalẹ Akinọla atawọn ọmọọsẹ rẹ meji nibẹ. Ni awọn ẹṣọ naa ba mu Akinọla atawọn oṣiṣẹ rẹ meji ọhun, Arikuyẹri Abdulrahman, ẹni ọdun mẹtalelogun, ati Habibu Ologun, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ninu ahere kan ti wọn fara pamọ si nitosi oko igbo ọhun.

Babafẹmi ni ninu ifọrọwerọ awọn pẹlu Akinọla lo ti jẹwọ fawọn pe oun gan-an ni Baálẹ̀ abule Kajọla, eyi to wa nitosi ibi to ti n ṣe ọgbin igbo gbigbin ọhun.

Ọna mẹta ni oko igbo ọhun, eyi to fẹrẹ to bii ogoji sare ilẹ wa, gbogbo rẹ ni ajọ NDLEA lawọn ti dana sun patapata loru mọju ọjọ naa.

Leave a Reply