Ileeeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe ki i ṣe pe ile Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho deede jona o, wọn ni awọn kan ni wọn waa dana sun ile ọhun, awọn janduku kan bayii ni.
Ninu atẹjade awon ọlopaa ti alukoro won, Gbenga Fadeyi, gbe jade ni won ti ṣalaye pe awọn araadugbo naa pe awọn lasiko ti wọn n jo ile naa. Wọn ni ohun ti wọn sọ fawọn ni pe awọn janduku kan ti de si adugbo awọn ni Soka o, ile Sunday Igboho ni wọn si wa, ati pe wọn n dana sun ile ọhun lọwọlọwọ.
Awọn eeyan ti wọn pe wọn yi ni wọn fi kun un pe awọn ko le jade, koda ẹnikẹni ko le jade, nitori niṣe ni awọn ti wọn waa sun ile naa n yinbọn soke kẹu kẹu, ti wọn n pariwo ẹni to ba to bẹẹ ko jade!
Lẹsẹkẹsẹ ti wọn ti gbọ ọrọ yii ni wọn ti jẹ ki ọga ọlopaa, iyẹn DPO, wọn ni Sanyo mọ, ti wọn si pe awọn panapana, bẹẹ ni wọn ni ki awọn ọlọpaa tete lọọ ba wọn. Fadeyi ni wọn pa ina naa loootọ, ṣugbọn awọn ibi kan ti jona. Oun naa lo ṣalaye pe iwadii n lọ lati wa awọn ti wọn ṣe iṣe buruku naa ri laipẹ rara.