Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Wahab Hammed, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati Adegoke Ayọbami, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ni wọn ti n ka boroboro lakolo ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun ipaniyan.
Lasiko ti kọmiṣanaa ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, n ṣafihan awọn afurasi naa laipẹ yii lo ti sọ pe lọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lawọn mọlẹbi Oguntade Wasiu lọọ fi to awọn ọlọpaa leti niluu Mọdakẹkẹ pe awọn n wa ọmọkunrin naa.
Ọlọkọde ṣalaye pe nigba ti iwadii bẹrẹ lọwọ tẹ Wahab Hammed to jẹ ọrẹ Wasiu, nigba ti ọrọ naa si de ẹka ọtẹlẹmuyẹ nipinlẹ Ọṣun ni Hammed jẹwọ pe Adegoke Ayọbami to n gbe lagbegbe Alaro, niluu Mọdakẹkẹ, naa mọ nipa rẹ, ti wọn si mu oun naa lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.
O ni awọn mejeeji mu awọn ọlọpaa lọ sinu igbo ti wọn pa Wasiu si, wọn si gbe oku rẹ, beẹ ni wọn ri ọkada rẹ gba nile Ayọbami.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Hammed ṣalaye pe iṣẹ ọkada loun n ṣe, oun si tun maa n ṣe iṣẹ Yahoo lẹẹkọọkan, ṣugbọn oun ko ti i maa ri owo nidii ẹ.
O ni iṣẹ Yahoo ni Wasiu n ṣe lati nnkan bii ọdun kan ati oṣu mẹta ti oun ti mọ ọn, ṣugbọn ọwọ rẹ ji sowo nidii iṣẹ naa, o si maa n sọ gbogbo nnkan meremere to maa n fi owo Yahoo ra foun.
O ni ẹdun ọkan leleyii maa n jẹ foun nigbakuugba ti Wasiu ba tun ti ri owo nidii iṣẹ naa, oun si maa n sọ fun Ayọbami tawọn jọ n ṣiṣẹ ọkada, ti awọn si pinnu pe o di dandan kawọn naa gba lara owo ọwọ Wasiu.
Lọjọ kan, Wasiu sọ fun Hammed pe oun fẹẹ ra ilẹ, gẹgẹ bi afurasi yii ṣe ṣalaye, o ni oun ati Ayọbami lẹdi apo pọ pe asiko ti to lati gba owo lọwọ oloogbe naa.
Wasiu lo fi ọkada rẹ gbe wọn lọ si agbegbe Alaro, ti wọn sọ pe ilẹ wa, bi wọn ṣe n fi ilẹ han an ni Ayọbami pajuda si i, to si n sọ pe kiakia, ko fun awọn lẹtọọ awọn ninu owo Yahoo to ni lakanti.
Nigba ti iyẹn fẹẹ maa ba wọn lo agidi ni Ayọbami fi ada ṣa a lori titi to fi ku. Wasiu mu foonu rẹ, bẹẹ ni Ayọbami gbe ọkada rẹ lọ sile.
Nigba ti iyawo Wasiu pe foonu ọkọ rẹ ni Hammed sọ fun un pe o ti lasidẹnti, ṣugbọn ohun ti iyawo rẹ n tẹnu mọ fun awọn ọlọpaa ni pe ọdọ Hammed lo dagbere lo jẹ ki wọn fura si ọmọkunrin naa titi to fi jẹwọ.
Ọlọkọde ṣalaye pe awọn afurasi mejeeji yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ wọn.