Faith Adebọla
Oludari agba ijọ Christ Revelation Church, ti wọn n pe ni Holy Promise, Biṣọọbu Ayọdeji Ipinmoroti, ti kede pe iran ti Ọlọrun fi han oun ni pe Naijiria ko ni i fọ si wẹwẹ, ati pe Aṣiwaju Bọla Tinubu ni yoo di aarẹ lẹyin Buhari.
Ninu iwaasu rẹ lọjọ Aiku, Sannde yii, Biṣọọbu Ayọdele sọ ni ṣọọṣi rẹ to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, pe ohun ti oun ri ni pe Tinubu maa di aarẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn alatilẹyin rẹ ni wọn maa kọyin si i ko too di asiko ibo gbogbogboo ọdun 2023.
O ni: “Ojiṣẹ Ọlọrun ni mi, ajihinrere si ni mi. Ọlọrun ran mi si Tinubu, temi ati ẹ ba foju rinju, ma a ṣalaye awọn adiitu kan fun un.
Ọlọrun ni Naijiria yii ko ni i fọ si wẹwẹ, ati pe Bọla Tinubu ni ẹni kan ṣoṣo to kaju ẹ ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023. Ọlọrun fi han mi pe oloootọ eeyan ni, o si mọ beeyan ṣe n ṣeto ilu daadaa, o ni iriri, o si lagbara iṣelu lati tukọ orileede yii debute ogo. Gẹgẹ ba a ṣe fi han mi, mo ri i pe ọpọ awọn alajọṣe ati ọmọlẹyin ẹ ni wọn dalẹ rẹ, sibẹ oun lo di aarẹ lọdun 2023.
Loootọ ni mo ri i pe rukerudo nla maa ṣẹlẹ nileeṣẹ Aarẹ wa, ṣugbọn Ọlọrun ko ran mi si Buhari.
Gbogbo iṣoro lo maa dopin lọjọ kan. Bi Tinubu ba fẹ, ko dije dupo aarẹ, oun ni wọn maa gb’ade fun, ọrọ-aje ilu yii si maa burẹkẹ si i. Ṣugbọn mo lawọn nnkan mi-in ti mo maa sọ foun nikan.”
Bẹẹ ni iran ti Biṣọọbu Ayọdele sọ poun ri o.