Adewumi Adegoke
Niṣe lọrọ di bo o lọ o yago laduugbo Idi-Apẹ, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn adigunjale ya bo adugbo naa, ti wọn si n rọjo ibọn ni kikan kikan.
ALAROYE gbọ pe ọkọ agboworin kan to n gbowo lọ ni Orita Idi-Apẹ. Ileewofowopamọ kan to wa nitosi Testing Ground, niluu Ibadan, la gbọ pe ọkọ agboworin naa ti n bọ. Eyi ni awọn adigunjale ọhun tori ẹ ya wọ adugbo yii.
Niṣe ni lilọ bibọ ọkọ duro, ti awọn to n wa mọto ko le lọ, bẹẹ ni awọn to n fẹsẹ rin pẹlu awọn ọlọkada n sa kijokijo, ti onikaluku n sa asala fun ẹmi rẹ. Ọpọ awọn eeyan mi-in fi mọto wọn silẹ lori ila nibẹ, ti wọn si sa lọ raurau.
Ko din ni ọlọpaa meji ti awọn adigunjale naa yinbọn pa, bẹẹ ni ibọn ba ọlọkada kan, to si wa ni ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun. Ibọn tun ba ọkunrin kan to wa ninu mọto rẹ jẹẹjeẹ. Apa ni aọn adigunjale naa ti yinbọn mọ ọn. Awọn to wa nitosi iṣẹlẹ naa ni wọn n sare wa mọto ti wọn yoo fi gbe ọkunrin ọlọkada naa, ki wọn le doola ẹmi rẹ.