Nibi t’Abiọdun ti n jale lawọn ọlọpaa ti mu un n’Ilaro 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Awọn ọlọpaa ẹkun Ilaro ti mu ọkunrin kan, Abiọdun Micheal, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ X1. Nibi to ti n digunjale lọwọ pelu awọn ẹgbẹ ẹ lọwọ ti ba a lopopona Polytechnic, n’Ilaro.

Ọjọ kejilelogun, oṣu kejila yii, lọwọ ba afurasi naa lẹyin ti olobo ta awọn ọlọpaa pe awọn ole kan ti di oju ọna to lọ si Poli Ilaro, wọn si n da awọn eeyan lọna, wọn n gba tọwọ wọn.

Nigba ti awọn ọlọpaa debẹ, awọn ole naa ko dúró, niṣe ni wọn sa lọ. Ṣugbọn ọwọ ba Micheal ni tiẹ.

Ibọn ilewọ meji, ọta ibọn mẹjọ pẹlu awọn oogun ibilẹ rẹpẹtẹ lawọn ọlọpaa gba lọwọ afurasi yii, CP Edward Ajogun si ti paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ sẹka iwadii iwa ọdaran, ki wọn si wa awọn yooku to sa lọ ri kiakia.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

Leave a Reply

//zeechumy.com/4/4998019
%d bloggers like this: