Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Obinrin ẹni ogoji ọdun kan, Abiye Friday, lo ti pade iku ojiji lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii pẹlu bi ẹnikan ti wọn porukọ ẹ ni Abidemi Oguntuyi ṣe gun un lọbẹ pa, nile ti wọn jọ n gbe laduugbo Ibaka, niluu Akungba Akoko, ipinlẹ Ondo.
Gẹgẹ bi ohun ta a fidi rẹ mulẹ latẹnu ẹnikan to jẹ ẹgbọn oloogbe ọhun ẹni to ni ka forukọ bo oun laṣiiri, o ni ede aiyede kan lo deedee bẹ silẹ laarin ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun naa eyi ti aburo oun fẹẹ ba wọn yanju.
O ni ko sẹni to le sọ ni pato idi ti Abidemi fi fi onija rẹ silẹ to si waa doju ija kọ Abiye to n gbiyanju ati pari ija fun wọn.
O ni kayeefi lo jẹ loju awọn nigba ti ọkunrin naa sare wọle lati fa ọbẹ yọ, eyi to fi gun aburo oun laya lọna bii mẹẹdogun.
Koda, ẹgbọn oloogbe kan ti wọn n pe ni John Friday gan-an tun fara gba ninu iṣẹlẹ naa pẹlu bi Abidemi ṣe gun un lọbẹ lapa nigba to n gbiyanju ati gba aburo rẹ silẹ lọwọ iku ojiji.
O ni loootọ lawọn eeyan kan sare gbe obinrin naa digba-digba lọ si ile-iwosan, ṣugbọn bi wọn ṣe dọhun-un lawọn dokita ti sọ fun wọn pe ẹni ti wọn gbe wa ti ku.
Ọsẹ to kọja yii ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo wọ afurasi ọdaran naa lọ s’ile-ẹjọ majisreeti kan niluu Akurẹ fun ẹsun ipaniyan ati igbiyanju lati paniyan.
Ẹsun mejeeji yii ni Simon Wada to jẹ agbefọba ni o tako abala okoo le lọọdunrun-un din ẹyọkan (319) ati ọta le lọọdunrun-un din marun-un (355) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Agbefọba dabaa ni oun dabaa ki wọn fi olujẹjọ ọhun pamọ s’ọgba ẹwọn Olokuta na ti ti t’ile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin Adeọla Kayọde ninu ọrọ tirẹ bẹbẹ fun sisun asiko diẹ ko le raaye fesi lori aba ti agbefọba fi siwaju adajọ.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ D. S. Ṣekoni ni k’awọn ọlọpaa si fi afurasi ọdaran ọhun pamọ si ọdọ wọn titi di ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun ta a wa yii.