Nibi ti Alhaji Beki ti n tọ nile wo pa a si niluu Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Baale ile ẹni ọdun mejilelaaadọta kan, Alhaji Taiye-Hassan Bẹki, lo pade iku ojiji lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, latari bi ile ṣe wo lu u nibi to ti n tọ laduugbo Alanamu, niluu Ilọrin.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagboole Bẹki, ti i ṣe ibi ti oloogbe naa n gbe. Ojo nla kan to rọ lọjọ Aje, Mọnde, lawọn eeyan lo fa a ti abala kan lara ogiri ile naa fi wo.

Ọkunrin to n ṣiṣẹ Redioniiki ọhun ni wọn lo bọ si ẹyinkule ile rẹ lati ṣẹyọ, nibi to duro si ni ogiri naa ti wo, to si mu gbogbo ile naa balẹ.

Wọn ni fun ọpọlọpọ iṣẹju lo fi ha sabẹ ile to wo lulẹ naa, ko too di pe wọn ri i gbe jade.

Lai fi akoko ṣofo, awọn mọlẹbi rẹ gbe e lọ silewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ẹpa ko pada boro mọ, ọsibitu naa lo dakẹ si.

Iwadii akọroyin wa fi han pe wọn ti sin oloogbe naa ni ilana Musulumi si itẹ awọn Musulumi to wa niluu Ilọrin.

Leave a Reply