Faith Adebọla, Eko
Ahamọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran meji yii, Ayuba Solomon, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ati David Manase, ẹni ogun ọdun pere, wa lọwọ yii, ibọn ni wọn ni wọn fi n jawọn eeyan lole loju popo, ibẹ si lawọn agbofinro ti ko wọn.
Bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, ṣe fidi ẹ mulẹ fun wa, agbegbe Agboju si Alakija, loju ọna marosẹ Eko si Badagry, lawọn afurasi ọdaran yii sọ di ibiiṣẹ wọn, ibẹ ni wọn ti n yọbọn sawọn ero ati onimọto loju popo, agaga ti sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ba ti ṣẹlẹ lagbegbe naa.
Eti awọn ọlọpaa ti kun fun oriṣiiriṣii ẹsun bawọn eeyan ti wọn n da lọna lagbegbe naa ṣe n waa fẹjọ wọn sun, ṣugbọn ti wọn o ri wọn mu.
Wọn lawọn ọlọpaa tẹsan Satellite ati Aguda lo dọdẹ awọn kọlọransi ẹda yii, nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, lọwọ tẹ wọn.
Obinrin kan lo figbe ta lẹyin ti wọn ja a lole tan, lawọn ẹruuku naa ba fere ge e, awọn ọlọpaa to wa nitosi ti wọn ti n ṣọ wọn naa si le wọn. Wọn ni wọn pọ, ṣugbọn awọn meji yii lọwọ ba ninu wọn.
Adejọbi ni lara awọn ẹru ti wọn ba lọwọ wọn ni ibọn ibilẹ kan, awọn ọta ibọn ati iboju meji ti wọn maa n wọ kawọn eeyan ma baa da wọn mọ.
Ninu iṣẹlẹ to pẹ eyi, ọwọ awọn agbofinro tun tẹ Ismail Abayọmi, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Ṣeun Akinbunu, toun jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn lọjọ Satide kan naa, nibi ti wọn ti n jale lopopona Ọlatunji Onimọle to wa nikorita Brown, l’Aguda.
Abilekọ Atinukẹ Adisa ni wọn lawọn a-lọ-kolohun-kigbe ẹda yii ṣẹṣẹ ja lole foonu Infinix-8 rẹ tan, wọn ni niṣe ni wọn fọ gilaasi ẹgbẹ ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna rẹ to ni nọmba Lagos AAA 30 AZ, ki wọn too fipa gba foonu ẹ.
Obinrin naa ati dẹrẹba rẹ, Apele Mohammed, ni wọn lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan Aguda leti, ki ọwọ too ba Ṣeun ati Abayọmi, ni wọn ba dero ahamọ, ahamọ ọhun ni wọn gbe de Panti, lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu ti paṣẹ kiwadii bẹrẹ lori wọn, ki wọn le tete foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.