Faith Adebọla, Eko
Ibanujẹ ati ọfọ nla ti ṣẹlẹ sawọn mọlẹbi akẹkọọ ọmọ ọdun mejidinlogun kan, Alade Ọba. Nibi tawọn aṣọbode atawọn onifayawọ ti n ba ara wọn ja ni ibọn tawọn kọsitọọmu n yin ti lọọ ba ọmọ ọhun, to si dagbere faye loju ẹsẹ.
Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ṣe sọ, ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye. Wọn ni nibi ti eruku ija ti sọ lala, ti ọta ibọn n fo kaakiri, ni aṣita ibọn ti da ẹmi ọmọ naa legbodo lẹsẹkẹsẹ.
Wọn ṣalaye pe awọn agbofinro to wa ninu ikọ JBPT (Joint Border Patrol Team) eyi to ni ṣọja, awọn aṣọbode ati awọn imigireṣọn ninu, ni wọn n patiroolu lọjọ buruku ọhun, bi wọn ṣe n lọ ni wọn n bọ lagbegbe Irosu, nitosi ibi tawọn ọlọpaa ti n yẹ iwe ọkọ wo ni Sawa, ni bọda Owode-Apa, Badagry, wọn n wa awọn onifayawọ to fẹẹ ko irẹsi tijọba ti fofin de kọja, lati mu wọn.
Bi wọn ti n ṣe eyi lọwọ ni wọn lawọn ọdọ kan lagbegbe naa ko ara wọn jọ, wọn si lọọ ba ikọ JBPT pe ki wọn kuro laduugbo awọn, wọn lawọn o le gba kawọn agbofinro naa ṣiṣẹ ti wọn ba wa ọhun lọdọ awọn.
Ọrọ yii lo dariwo laarin awọn ọdọ ọhun, tawọn kọsitọọmu fi bẹrẹ si i yinbọn kaakiri lai bikita, ibẹ si ni ọta ibọn kan ti lọọ ba Alade Ọba nibi to duro si, to si ṣeku pa a loju ẹsẹ, lawọn agbofinro ba gbe oku rẹ si mọto wọn, wọn fẹẹ maa gbe e lọ.
A gbọ pe ileewe girama Kankou Secondary School, lọmọ naa n lọ, ipele kẹta agba (SS3) lo wa, ọdun yii ni iba pari ẹkọ rẹ nileewe ọhun.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o mu kawọn ọdọ to ku gbana jẹ, ti wọn si bẹrẹ si i sun taya laarin titi, wọn lawọn o ni i gba ki wọn gbe oku ọmọ ohun lọ.
Nigba ti ọrọ yii to ọga ṣọja ileeṣẹ ologun 243 Recce Battalion, to wa n’Ibẹrẹko, Ọgagun Nicholas Rume, leti, oun atawọn ṣọja to ko sodi waa ba wọn da si i, awọn aṣọbode naa si yọnda oku naa fawọn mọlẹbi oloogbe ọhun.
Ọgbẹni David Aladeotan to niṣẹlẹ ọhun ṣoju oun sọ pe oko agbọn ni oloogbe naa ti n bọ, ko si lara awọn ti wọn n fa wahala rara ti ibọn fi ba a.
O ni, “Pẹlu bawọn agbaagba atawọn olori agbegbe naa ṣe sọ fawọn kọsitọọmu pe ko si irẹsi ajeji kankan laduugbo awọn, sibẹ wọn kọ, wọn ko gba, afigba ti wọn fibọn ṣọṣẹ yii, bẹẹ wọn ko ri irẹsi kankan mu.
O ni nigba ti wọn ko ri irẹsi ti wọn lawọn n wa ni wọn tun bẹrẹ si i mu ọkada tawọn eeyan gbe siwaju ile wọn, wọn fẹsun kan wọn pe wọn n lo ọkada naa fun iṣẹ fayawọ ni, eyi lo mu kawọn ọdọ ati ẹgbẹ ọlọkada yari fawọn agbofinro naa.
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ kọsitọọmu, kọmandi ti ẹnubode Sẹmẹ, Ọgbẹni Abdullahi Hussain, ni bẹẹ kọ lọrọ ọhun ri, o lawọn onifayawọ kan ti wọn gba ọna ẹlẹsẹ ninu igbo ni wọn ṣakọlu sawọn kọsitọọmu niluu Irolu, latari bawọn ṣe gbegi dina fun wọn nigba ti wọn n fi ọkada ṣe fayawọ irẹsi tijọba fofin de.
O lawọn yii naa ni wọn lọọ pe awọn ọdọ bii aadoje lati waa ba awọn agbofinro ja, wọn bẹrẹ si i ju okuta, igi ati awọn nnkan ija mi-in lu mọto kọsitọọmu ati awọn agbofinro naa. O nigba ti wọn gbiyanju lati dana sun mọto ijọba ọhun lawọn kọsitọọmu bẹrẹ si i yinbọn soke lati le wọn sa, ti ọta ibọn si lọọ ba olori awọn onifayawọ ọhun.
O ni irọ lawọn to pe oloogbe naa lọmọ ileewe n pa, ki i ṣe oko lo ti n bọ, ọkan lara awọn onifayawọ ni, aarin wọn lo duro si.
Hussain ni omi alaafia agbegbe naa ti n toro.