Nibi ti nnkan le de bayii, a ko mọ bi a ṣe maa ba araalu sọrọ mọ o- Emir Oke-Ọya

Adewale Adeoye

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn Emir Oke-Ọya, labe ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘Northern Traditional Council’ (NTC), eyi ti Emir ipinlẹ Kaduna, Alhaji Muhammad Sa’ad Abubarkar 111, jẹ alaga ẹgbẹ ọhun ti panu-pọ lati sọ fawọn alaṣẹ ijọba orileede yii pe ilu le gidi, ki wọn wa nnkan ṣe si bi awọn ọdọ ilu ko ṣe ri iṣẹ ṣe, ti ko si eto aabo fawọn araalu, ti gbogbo nnkan si dorikodo lorileede yii. O ni awọn tawọn jẹ Emir, aṣaaju ẹsin, tawọn ọdọ ọhun n bọwọ fun nigba gbogbo lawọn n pẹtu si wọn lọkan lati ma ṣe ṣewọde ita gbangba, tabi fa wahala laarin ilu bayii.

Alhaji Muhammad Sa’ad Abubarkar sọrọ ọhun di mimọ lasiko ipade pataki kan tawọn lọba-lọba ẹya Hausa, ẹlẹẹkẹfa iru ẹ, eyi to waye niluu Kadunam l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2024 yii.

Sultan ọhun ti ko pẹ ọrọ naa sọ rara lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade wọn sọ pe awọn tawọn jẹ Emir, aṣaaju ẹsin atawọn gomina ipinlẹ lawọn n pẹtu sọkan awọn ọdọ gbogbo to wa niluu pe ki wọn ni igbagbo ninu ijọba orileede yii, ṣugbọn ni bayii, iṣẹ ati iya ọhun ti pọ ju ohun tawọn le ni ki wọn maa fara da lọ mọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘‘O ti de gongo bayii tawọn Emir, aṣaaju ẹsin ati awọn gomina ipinlẹ kọọkan ko le bawọn ọdọ ti inu n bi lori bi nnkan ṣe n lọ laarin ilu sọrọ mọ. A ko mọ irọ tabi awawi kankan ta a le sọ fun wọn mọ. Gbogbo igba la maa n sọ pe ki wọn ṣe suuru fawọn alaṣẹ ijọba orileede yii, ọrọ naa ko fẹẹ ta leti wọn mọ, nitori pe ẹni ti ebi n pa ko le gbọrọ meji mọ o. Ko si iṣẹ, ko si ounjẹ gidi ti wọn le jẹ, bẹẹ ni ko si eto aabo gidi laarin ilu mọ. Igba gbogbo lawọn agbebọn fi n ṣoro bii agbọn laarin ilu. Bẹẹ awa ta a jẹ Emir ati aṣaaju ẹsin la n ba awọn ọdọ langba sọrọ nigba gbogbo pe ki wọn ṣe suuru, pe ilu maa daa laipẹ yii, ṣugbọn ko si apẹẹrẹ pe nnkan maa daa rara. Igba gbogbo ni nnkan fi n buru si i, igbe ilu ko fara rọ mọ lawọn ọdọ n pa, bẹẹ awa ta a jẹ olori ilu paapaa mọ pe oootọ lawọn ọdọ naa n sọ.

A ko gbọdọ fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn ọdọ yii rara, awọn lo nilu, bẹẹ bi wọn ba fa ibinu wọn yọ tan, apa awa ta a n ṣejọba le wọn lori le ma ka a mọ. Adura mi ni pe, a ko ni i ji lọjọ kan ka ri i pe awọn ọdọ ilu ta a n bẹ ti yiju pada si wa, ti wọn ti n fẹhonu han. Ti wọn ko si ni igbagbọ ninu wa mọ. O ti waa doju rẹ bayii, ebi n pa awọn araalu gidi, bẹẹ ni inu n bi wọn gidi, nnkan to n kapa awọn ọdọ naa ni pe wọn nigbagbọ ninu wa pe a le ba awọn alaṣẹ ijọba orileede yii sọrọ, ki wọn gbọ si wa lẹnu ni. Ba a ṣe n ba wọn sọrọ, bẹẹ la a n bẹ Ọlọrun Ọba pe ko da sọrọ orileede yii.

 

Leave a Reply