Tinubu, awọn gomina fọwọ si idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ

Jọkẹ Amọri

Nibi ipade pajawiri kan ti ijọba apapọ ati awọn gomina kaakiri ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji to wa nilẹ wa ati Aarẹ ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii, ni gbogbo wọn ti gba lati da awọn ọlọpaa ipinlẹ silẹ ki amojuto le ba eto aabo to ti mẹhẹ nilẹ wa.

Wọn fẹnu ko lori ọrọ yii nibi ipade ti awọn ati Aarẹ Bọla Tinubu ṣẹ niluu Abuja. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i fẹnu ọrọ jona lori bi igbesẹ naa yoo ti lọ ati ọna ti wọn yoo gbe e gba, gbogbo wọn ni wọn ti gba pe ki idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ  wa bayii.

Nibi ipade pajawiri naa to waye nile ijọba, ninu eyi ti Aarẹ Bọla Tinubu ati Igbakeji rẹ, Kashim Shettima, wa ni wọn ti sọrọ ọhun.

Bakan naa ni wọn sọrọ lori ọda ounjẹ to n ba awọn eeyan orileede yii finra, ti wọn si ti gbe igbimọ kalẹ ti yoo ṣẹ amojuto bi ayipada yoo ṣe wa lori eleyii atawọn ipinnu wọn lori awọn koko ti wọn mẹnu ba nibi ipade ọhun.

 

Nigba ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade yii, Minisita fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Idris Muhammed, ṣalaye fawọn akọroyin pe ọkan-o-jọkan ipade lo ti n lọ lọwọ bayii lati mọ ọna ti wọn yoo gbe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun gba, ati bi ohun gbogbo yoo ṣe lọ. Idris ti awọn gomina Plateau, Kaduna ati Delta kọwọọrin pẹlu rẹ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe loootọ ni awọn pinnu lati da ọlọpaa ijọba ipinlẹ silẹ, ti awọn ti gbe igbimọ dide, ṣugbọn ki i ṣẹ pe ipinnu tabi igbesẹ kan gboogi ti i waye lori eleyii. O ni pẹlu ẹ naa, awọn yoo ṣiṣẹ tọ ipinnu naa lẹyin lati ri i pe o wa si imuṣẹ.

Wọn ni ṣiṣe idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ yoo jẹ ki awọn agbofinro wa ni arọwọto awọn eeyan, ti yoo si mu ki wọn gbadun iṣẹ ọlọpaa si i ju bo ṣẹ wa tẹle lọ, ti awọn ara agbegbe kọọkan naa yoo si le da si ọrọ eto aabo laduugbo wọn.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ninu wọn gba pe ṣiṣẹ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ yii yoo jẹ ki awọn adari kan maa ṣi agbara lo, paapaa ju lọ lawọn ipinlẹ to ba jẹ aọn ni wọn n dari rẹ.

Lara awọn ohun ti wọn tun sọrọ le lori ni erongba wọn lati fi kun awọn aṣọgbo, ki awọn si ro wọn lagbara lati le maa mojuto awọn oko ọba ati awọn aala lati ipinlẹ kan si omi-in.

Nipa ti ọwọngogo ounjẹ, Idris ni Tinubu ti paṣẹ fun awọn ẹṣọ alaabo gbogbo nilẹ wa lati gbogun ti awọn ti wọn n ko ounjẹ pamọ, eyi ti ko jẹ ki awọn araalu ri i ra bo ṣe yẹ. O paṣẹ fun ọga ọlọpaa patapata, ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati ṣiṣẹ pẹlu awọn gomina, ki eleyii le di mimuṣẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP naa kin idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lẹyin, ṣaaju ipade ti Aarẹ ṣe pẹlu awọn gomina yii. Wọn ni eleyii yoo ran awọn gomina lọwọ lati mojuto eto aabo nipinlẹ koowa wọn.

Leave a Reply