Faith Adebọla, Eko
Boroboro bii ẹni ti wọn da omi gbigbona si lẹnu lawọn gende afurasi ọdaran mẹta kan n ka bi wọn ṣe de teṣan ọlọpaa, wọn jẹwọ pe awọn lawọn wa nidii idigunjale, jija foonu gba ati iwa ọdaran to n waye lagbegbe Ketu si Ikorodu, nipinlẹ Eko.
Orukọ awọn mẹtẹẹta ni Sunday Ọlanrewaju, ẹni ọdun mẹtalelogun, Ṣeyi Ọmọtọshọ, ẹni ọdun mọkandinlogun, ati Damọla Ajewọle, ọmọ ọdun mẹtadinlogun. Ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa RRS lo le wọn mu nibi ti wọn ti n sa lọ ni nnkan bii aago mọkanla aabọ oru Ọjọbọ, Tọsidee yii.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fi ṣọwọ s’ALAROYE lori ọrọ ọhun, o ni bawọn ikọ RRS naa ṣe n fimu finlẹ, ti wọn n patiroolu kiri agbegbe Agidingbi, n’Ikẹja, lati sọ awọn janduku ti wọn n fi pọpọṣinṣin ọdun boju lati ja awọn ero ọkọ ati onimọto lole, bẹẹ lawọn afurasi ọdaran naa fere ge e bi wọn ṣe kofiri awọn ọlọpaa yii, ọkada dudu kan ni wọn gun sa lọ.
Wọn lawọn ọlọpaa naa gba ya wọn, ibi ti wọn ti n sare buruku lọ lọkada wọn ti takiti, wọn fi ọkada silẹ, wọn fẹẹ bẹ lugbẹ, ṣugbọn meji ninu wọn ti fara gbọgbẹ lẹsẹ ati imu, ibi ti wọn si ti n ra pala lati dide lọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn mẹtẹẹta ati ọkada ti wọn gbe wa.
Ni teṣan, wọn jẹwọ pe jija foonu ati baagi gba, idigunjale, jiji ọkada niṣẹ tawọn n ṣe, ati pe agbegbe Iṣhẹri, Berger, Ketu, Ikẹja, Ogudu, Alapẹrẹ lọọ de Ikorodu lọwọ awọn ti maa n dẹ ju lọ.
Ọkada ti wọn gbe wa ko ni nọmba, wọn si jẹwọ pe awọn ji i ni, oun lawọn n lo lati fi ṣiṣẹ buruku naa. Bẹẹ ni wọn tun ba ọbẹ ati foonu lara wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe ki wọn fi awọn mẹtẹẹta ṣọwọ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iwadii siwaju si i, wọn lawọn ti tọju ọkada wọn atawọn nnkan mi-in ti wọn ba lara wọn gẹgẹ bii ẹri nigba ti igbẹjọ ba bẹrẹ.