Nibi ti Tiamiyu ti n ṣiṣẹ ninu kanga lo ti ku sinu ẹ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin oniṣẹ ọwọ kan, Sikiru Tiamiyu, ẹni ọdun mejidinlogoji, lo mu omi ku ninu kanga kan laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lagbegbe Dada Estate, niluu Oṣogbo.

Iṣẹlẹ naa lo da hilahilo ati ipaya silẹ laarin awọn araadugbo yii nitori o jẹ ẹlẹẹkeji iru ẹ laarin ọjọ mẹtadinlogun siraa wọn.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin oniṣẹ-ọwọ kan ti a ko mọ orukọ rẹ ti kọkọ gan mọ inu kanga naa lasiko to n tun ẹrọ afami (Pumping machine) inu ẹ ṣe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Bakan naa leeyan meji mi-in tun fara pa ninu iṣẹlẹ mejeeji yii, ti wọn si n gbatọju lọwọ nileewosan.

A gbọ pe bi iṣẹlẹ ti aarọ yii ṣe ṣẹlẹ ni awọn araadugbo ti pe awọn oṣiṣẹ panapana ijọba ipinlẹ Ọṣun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro fun ajọ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ibrahim Adekunle, ni oku Tiamiyu ni wọn gbe jade ninu kanga naa, nigba ti wọn gbe ọkunrin keji lọ sileewosan.

Adekunle ṣalaye pe, “Loni ọjọ Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla ọdun 2022, awa oṣiṣẹ panapana gba ipe kan lati Zone 5A, Oke Arungbo Community, Dada Estate, niluu Oṣogbo, laago mọkanla ku iṣẹju mẹẹẹdogun aarọ pe awọn ọkunrin meji ha sinu kanga kan nibẹ.

“Awọn oṣiṣẹ wa, ti Adegoke Sẹsan (PFS), ko sodi lọ sibẹ. Wọn gbe awọn mejeeji jade, ẹni kan ti ku, wọn si gbe oku rẹ fun awọn ọlọpaa, awọn araadugbo gbe ọkunrin keji lọ sileewosan fun itọju ni tiẹ.

“Ọgbẹni Sikiru Taiwo Tiamiyu ni ọkunrin to ku, o si n ba wọn tun kanga naa ṣe lọwọ lo pade iku ojiji rẹ.

“Bakan naa ni iru iṣẹlẹ naa waye nibi kanga yii kan naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii. Ṣe ni oniṣẹ ọwọ yẹn n ṣiṣẹ lara ẹrọ ifami kanga naa to fi gan mọna, to si ku lọju-ẹsẹ. Awọn araadugbo ni wọn si gbe ọkunrin ti wọn jọ n ṣiṣẹ lọ sileewosan fun itọju lọjọ naa lọhun-un”

Leave a Reply