Nibi ti wọn paaki tirela to kun fun ororo si ni ọkunrin yii ti ji i gbe lọ

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, ni ọgbẹni kan tawọn ọlọpaa lawọn ko fẹẹ darukọ rẹ sita nitori ti iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa rẹ wa bayii, ẹsun tawọn agbofinro fi kan an ni pe o ji mọto tirela DAF kan pẹlu ororo to wa ninu rẹ gbe nibi ti dẹrẹba ọkọ naa paaki rẹ si.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni afurasi ọdaran ọhun ji mọto tirela naa ti ororo tiye rẹ jẹ ọgbọn miliọnu Naira wa ninu rẹ gbe ni gareji Maraban, tawọn dẹrẹba ọkọ tirela maa n paaki si lati sinmi ranpẹ niluu Jos.

ALAROYE gbọ pe lati ilu Umuahia, nipinlẹ Abia, ni dẹrẹba ọkọ tirela ọhun ti n gbe ororo  lọ si Kano, to si duro si gareeji Maraba, lati wẹ, ṣugbọn nigba to fi maa bọ sita, ko ba mọto tirela rẹ mọ nibi to paaki rẹ si. Loju-ẹsẹ lo ti figbe bọnu, tawọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku si lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa agbegbe naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bauchi, S.P Ahmed Muhammad Wakili, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe loju-ẹsẹ tawọn ti gba ipe pajawiri kan lati ọdọ awọn araalu lawọn ti bẹrẹ si i ṣewadi nipa iṣẹlẹ ọhun, tọwọ si pada tẹ afurasi ọdaran ọhun lasiko to n wa ọkọ ọhun lọ.

Atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni dẹrẹba ọkọ tirela kan paaki sagbegbe Maraba, niluu Jos, ibẹ lọpọ awọn dẹrẹba ọkọ tirela to n rin-irin-ajo maa paaki si fun isinmi ranpẹ, dẹrẹba ọkọ tirela naa fẹẹ wẹ ni, nigba to maa bọ sita, ko ba mọto rẹ mọ nibi to paaki rẹ si, lo ba figbe bọnu loju-ẹsẹ, ilu Umuahia nipinlẹ Abia, lo ti n bọ, ipinlẹ Kano lo n gbe ọja ororo tiye rẹ jẹ miliọnu lọna ọgbọn Naira lọ, ṣugbọn ipinlẹ Bauchi ni afurasi ọdaran to ji mọto tirela naa n gbe e lọ kọwọ too tẹ ẹ.

Alukoro ni awọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ,  ko le ṣalaye ohun to ri to fi gbe mọto onimọto lọ.

 

Leave a Reply