Nibi ti wọn ti n ja sokuu ẹran, Lukman ge ika iyaale ile sọnu l’Omu-Aran

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo ti ju Azeez Lukman sẹwọn ọdun meje fẹsun pe o ge ika arabinrin Muyibat o tun ṣa ọmọ rẹ ladaa.

Iṣẹlẹ naa waye niluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara. Niṣe ni Lukman ati Abeeb n ja lori ẹran ti ọkọ gba ti wọn din jẹ. Ẹran ọhun lo fa wahala laarin wọn, ti Lukman si sa Habeeb ladaa lori. Lasiko ti Muyibat sare wa lati da sija naa ni Lukman tun fi ada ge ika rẹ ja bọ.

Onidaajọ Yusuf Adebayọ ni Lukman jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, fun idi eyi, ko lọọ fi ẹwọn ọdun meje jura.

 

 

Leave a Reply