Nibi tọkunrin yii ti fẹẹ tu nnkan lara aloku mọto lo ku si n’Idiroko

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kejila, ọdun 2021 yii, ni ikọ fijilante So-Safe, nipinlẹ Ogun, ri oku ọkunrin kan to ku sabẹ mọto lagbegbe Agọ Egun, n’ijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun. Nibi to ti fẹẹ tu nnkan lara aloku ọkọ naa lo dagbere faye si.

Ko sẹni to mọ orukọ ọkunrin to doloogbe naa, tabi ibi to ti wa.

Alaye ti ikọ So-Safe ti Kọmandanti Sọji Ganzalo n dari ṣe ni pe nibi ṣọọbu mẹkaniiki kan ti ẹnikẹni ko ṣiṣẹ nibẹ lati bii ọdun meji ni ọkunrin yii ti lọọ tu nnkan lara ọkọ.

Wọn ni ẹni to ni ilẹ naa ti n wa mẹkaniiki to n lo ibẹ tẹlẹ pe ko waa gbe mọto ayọkẹlẹ ti nọmba ẹ jẹ PKA 579 AA ọhun kuro nibẹ, ṣugbọn wọn ko gburoo rẹ.

Afi bi afurasi ole yii ṣe ko irinṣẹ ti wọn fi n tu nnkan lara ọkọ lọ sibẹ, to si bẹrẹ si i pitu ọwọ rẹ nigba ti ẹnikẹni ko ri i.

Boya ko ba ma sẹni ti yoo tilẹ mọ pe o ṣọṣẹ kankan nibẹ bi ko ba ṣe pe o pade iku ojiji ni. Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe irinṣẹ kan to fẹẹ fi gbe ọkọ naa soke (jack) lo daṣẹ silẹ lojiji, wọn ni eyi lo mu ki mọto naa pada sisalẹ, to wo lu ole yii lori, to si ṣe bẹẹ pade iku ojiji labẹ mọto, ti ẹsẹ rẹ mejeeji wa nita, ti ori rẹ soke lọhun-un, si wa labẹ mọto.

Atẹjade ti Alukoro So-Safe, Mọruf Yusuf, fi sita lori iṣẹlẹ yii sọ ọ di mimọ pe awọn fijilante ti gbe oku naa pẹlu awọn irinṣẹ to fẹẹ fi jale lọ si ẹka olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa n’Idiroko, fun itẹsiwaju iwadii.

Leave a Reply