Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Okere tan, eeyan mẹta ni wọn ti ṣeku pa nibi ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lagbegbe Kankatu, Okelele, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Aje, Mọnde, si ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fija pẹẹta ni agbegbe naa, ti wọn si yinbọn pa ọkunrin kan, AbdulGaniy, ti ọpọ eniyan mọ si ‘Messi’.
Bakan naa, ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni awọn afurasi to jẹ ẹlẹgbẹ AbdulGaniy ti wọn pa lọọ gbesan iku ọkan ninu wọn yii, ti wọn si pa arakunrin kan ti wọn n pe ni Adebayọ Yitta, nidii ofi to ti n hun aṣọ.
Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe lẹyin ti wọn yin Adebayọ nibọn tan ni wọn tun n ṣa a ladaa titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.
Siwaju si, wọn tun ṣeku pa Lanre, lọjọ Tusidee yii kan naa, lagbegbe Kankatu, si Okelele, niluu Ilọrin.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ajayi Okasanmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn yoo ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori ẹ, awọn yoo si fi to awọn oniroyin leti.
Magaji agbegbe Ibagun, ni Okelele, niluu Ilọrin, Malam Sakariyau Ilufẹmiloye, bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ṣe ya bo agbegbe naa, ti wọn si n rẹ ara wọn danu bii ila, oju-ẹsẹ lo pe ipade pajawiri pẹlu awọn olori ẹbi atawọn igbimọ ẹṣọ alaabo lagbegbe naa ki wọn le wa ọna abayọ si iṣoro to n ba wọn finra.