Gbenga Amos, Abẹokuta
Olowo ẹni ki i roro titi ko ni ka ma ṣu, idi la o ni i duro nu, bẹẹ lawọn agba n powe latijọ, ṣugbọn lanlọọdu ẹni ọdun marundinlaaadọrin yii, Samuel Adekọya, ko tẹle owe yii, tori awọn ọmọ tẹnanti ẹ yagbẹ sibi ti ko fẹ, lo ba so awọn ibeji naa lọwọ lẹsẹ bii ẹran ti wọn fẹẹ pa, o yọ waya ina ti wọn, o lu wọn lalubami.
Abilekọ Gbemisọla Olishe, iya Taiwo Enoch Olishe ati Kẹhinde Emmanuel Olishe, ni wọn lo sare janna janna lọọ fẹjọ lanlọọdu ẹ sun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin yii, ni teṣan ọlọpaa to wa ni eria kọmandi Ijẹbu-Ode.
Gbemisọla ṣalaye fawọn ọlọpaa pe alaaanu ara Samaria kan tawọn jọ n gbe adugbo lo ṣẹṣẹ pe oun lori aago pe niṣe ni lanlọọdu oun so awọn Taye-Kẹyin toun fi silẹ nile mọle bii ẹran iso, lo ba mu wọn lu bii ewurẹ.
Oju ẹsẹ ni Eria Kọmanda teṣan naa, ACP Adeniyi Ọmọsanyin, ti yan awọn ọlọpaa kan lati tẹle obinrin naa lọ sibi iṣẹlẹ ọhun. Nigba tawọn ọlọpaa de’bẹ, iyalẹnu lo jẹ pe loootọ ni wọn ba awọn ibeji tọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkanla lọ ọhun lori iso, niṣe ni lanlọọdu so wọn lọwọ ati ẹsẹ bii maaluu.
Wọn tun ri apa ẹgba loriṣiiriṣii lara awọn ọmọ ọhun, ọkan ninu wọn si ti fẹsẹ ṣeṣe, ẹjẹ n jade lara ẹ, wọn nibi ti lanlọọdu ti n wọ ọ nilẹ niwọọkuwọọ lo ti fara pa.
Awọn ọlọpaa tu awọn ọmọ naa, wọn si sare gbe wọn lọ si ọsibitu Jẹnẹra, n’Ijẹbu-Ode. Ẹka to n tọju awaọn alaisan pajawiri ni wọn gbe ọkan lara awọn ibeji ọhun si, tori o ti fara gbọgbẹ gidi lọwọ ọdaju lanlọọdu yii.
Awọn ọlọpaa tun ri fidio ti ẹnikan ya, to ṣafihan bi lanlọọdu naa ṣe n wọ awọn ọmọ ọhun, bo ṣe n ko waya bo wọn, to si ṣe awọn ọmọ yii yankan yankan.
Wọn fọwọ ṣinkun ofin mu lanlọọdu yii, ṣugbọn ki wọn too mu un lọ, wọn bi i leere ẹṣẹ tawọn ọmọọlọmọ ṣẹ to fi sọ wọn di siso mọlẹ, o ni wọn o ṣẹ oun lẹṣẹ kan ju pe wọn yagbẹ si ayika ile oun, ọpọ igba loun si ti kilọ fun wọn ati awọn obi wọn pe oun o fẹ iru imikimi bẹẹ layiika oun, tori ajiṣefinni ẹda loun.
Wọn ni ko fi ibi tawọn ọmọ naa yagbẹ si han awọn, o lawọn ọmọ naa ti fọ ọ kuro, lẹyin ti wọn fọ ọ kuro loun ṣẹṣẹ waa da sẹria fun wọn yii.
Ṣa, ọrọ yii ti detiigbọ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, o si ti paṣẹ pe ki wọn tete fi Saamu abọlọmọ-ba-a-wi yii ṣọwọ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣofintoto iwa ọdaran abẹle bii eyi.
O ni ti wọn ba ti pari iwadii wọn, ile-ẹjọ lo maa ba wọn pari ọrọ naa.