Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo eyan ilu Ijẹlu-Ekiti, nijọba ìbílẹ̀ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti, pẹlu bi ojo nla kan ṣe ṣi ile to to bii ọgbọn niluu naa.
Bakan naa ni ilu odi keji, Omu-Ekiti, ko din ni ile mejilelogun ti iji lile naa ṣi sọnu lakooko ojo nla kan to mu iji lile dani, ti ko si rọ ju ọgbọn iṣẹju lọ.
Bii ọgọrun-un eeyan ni ojo ọhun ti sọ di alainile lori, to si jẹ pe niṣe ni wọn n wa’bi wọ si bii adiyẹ.
Awọn eeyan ilu naa ṣalaye fun akọroyin wa pe o ti to oṣun kan ti wọn ti ọjọ ti rọ kẹyin niluu mejeeji yii, eyi to si ko ipaya ba awọn eeyan naa.
Ṣugbọn ojo nla to bẹrẹ ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, ti wọn ro pe yoo mu itura ba wọn ko rọ ju ọgbọn iṣẹju lọ ti wahala fi bẹrẹ. Niṣe lojo naa mu ọwọ agbara wa, to n fẹ atẹgun lile. Lasiko naa lo bẹrẹ si i ṣi awọn orule ile kaakiri, bakan naa lo wo ogiri ile, leyii ti ko yọ aafin Ọba Isaac Ajayi Adetoyinbo, Onijẹlu ti Ijẹlu-Ekiti, ile ijọsin ati ileewe to wa niluu naa silẹ.
Lasiko ti Igbakeji gomina ilu naa, Arabinrin Monisade Afuyẹ, ṣabẹwo si ilu naa, o kẹdun pẹlu awọn eeyan ilu ọhun, o si ṣeleri pe ijọba ipinlẹ naa yoo ṣe ohun gbogbo lati ṣeranlọwọ fawọn ti ojo naa ṣi ile wọn.
Igbakeji gomina ọhun ṣalaye pe inu oun dun pe ko si ẹmi to sọnu tabi ẹni to farapa ninu iṣẹlẹ naa. Afuyẹ waa paṣẹ pe ki awọn ti wọn ṣi n gbe ninu ile ti ojo ti wo ku yii ki wọn kuro nibẹ lati dẹkun ki ogiri alapa ile naa ma baa tun wo pa wọn.
Igbakeji gomina waa rọ awọn eeyan ilu naa lati maa gbin igi si agbegbe ati ayika wọn lati dẹkun iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.
O ni, “Iṣẹlẹ ibanujẹ niyi, ṣugbọn ijọba ipinlẹ Ekiti yoo ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn ka awọn ile ti iji lile yii fọwọ ba, ijọba gbọdọ ri i pe wọn ran yin lọwọ lati le kọ awọn ile ti iji yii bajẹ pada.
“A dupẹ lọwọ Ọlorun pe ko si ẹnikankan to ku ninu iṣẹlẹ yii, ṣugbọn a n rọ yin pe ki ẹ maa gbin igi si ayika yin, eyi yoo maa da ọwọ iji lile bii eleyii duro.
“Awọn ọba wa gbọdọ maa ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn da awọn eeyan wa lẹkọọ idi pataki to fi yẹ lati maa gbin igi si ayika wọn.”
Bakan naa ni Omu-Ekiti, ilu kan ti ko jinna si Ijẹlu –Ekiti, naa fara gba ninu iji lile ti ojo ọhun mu lọwọ. Ile ti ko bii marundinlọgbọn ni ojo naa fọwọ kan. Ọba ilu ọhun, Adeyẹye Ogundeji, gboṣuba fun igbakeji gomina Ekiti fun abẹwo pajawiri to ṣe siluu naa lẹyin wakati diẹ ti iṣẹlẹ naa waye.
Bakan naa ni aṣofin to n ṣoju agbegbe naa nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti, Ọnarebu Idowu Ọdẹbunmi, ṣeleri pe ijọba ipinlẹ naa yoo ṣe ohun gbogbo lati ri i pe wọn pese iranwọ fun awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ naa.
O fi da wọn loju pe ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Ekiti, yoo wa lati waa ṣe akọsilẹ awọn ile ti iṣẹlẹ naa fọwọ ba ni ilu mejeeji.