Wọn ti ko ‘ma-mu-gaari’ si Abubakar lọwọ, ọlọpaa lo fọ leti n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fi panpẹ ofin gbe afurasi kan, Abubakar Mahmud, ẹni ọdun marundinlogoji (35), to n gbe ni agbegbe Ọlọ́runsògo, niluu Ilọrin, fẹsun pe ṣe lo fọ ọlọpaa obinrin kan, Janet Anthonia, to wa lẹnu iṣẹ rẹ leti.

ALAROYE gbọ pe lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Alubarika Taofeek, to n gbe ni agbegbe Gàá-Odòtà, mu, ẹsun lọ si agọ ọlọpaa kan to wa ni agbegbe Adéwọlé, niluu Ilọrin, pe lasiko toun n kọja lọ lagbegbe Gèrí-Álímì, niluu Ilọrin, ni oun ri Abubakar to n ṣakọlu si obinrin ọlọpaa kan, Janet, to n fọ ọ leti tohun ti aṣọ ọlọpaa lọrun rẹ.

Lẹyin eyi ni ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ki wọn lọọ fofin gbe Abubakar, ki wọn si foju ẹ bale-ẹjọ, nitori ko sẹni to lẹtọọ lati fiya jẹ ọlọpaa to wa ninu aṣọ, ati lẹnu iṣẹ, bo ti wulẹ ki ohun to ṣe dun eeyan to.

Agbefọba, ASP Abọṣẹde Yusuf, ti waa gbe iwe ẹsun afurasi lọ siwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nibi ti yoo ti ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Leave a Reply