Ko yẹ ki ọmọ ti ko ba pe ọdun mejidinlogun wọ ileewe giga fasiti mọ-Minisita

Monisọla Saka

Ijọba apapọ ti paṣẹ pe wọn ko gbọdọ gba akẹkọọ yoowu ti ko ba ti i pe ọdun mejidinlogun sileewe giga.

Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Tahir Mamman, ti i ṣe minisita feto ẹkọ sọrọ naa di mimọ lasiko ti wọn lọọ ṣabẹwo sibudo ti wọn ti n ṣedanwo igbaniwọle sileewe giga, Unified Tertiary Matriculation Examination (UTME), lagbegbe Bwari, niluu Abuja.

Mamman ni ọdun mejidinlogun yii, lo wa nibaamu pẹlu ipele ati ọdun eto ẹkọ kọọkan lati ileewe alakọọbẹrẹ, iyẹn 6-3-3-4. O bu ẹnu atẹ lu iwa awọn obi kan ti wọn maa n duro lori pe kawọn ọmọ wọn ti ko ti i toju bọ wọle sile ẹkọ giga.

“Ki wọn ba awọn obi sọrọ lati ma maa ti awọn ọmọ wọn gbọn-ọn gbọn-ọn, nitori wahala pe kọmọ wọle ni dandan lati ọdọ awọn obi lo n fa eleyii.

Ọdun to kere ju tọmọ le wọle ẹkọ giga ni ọdun mejidinlogun, ṣugbọn a ti ri ọmọ ọdun mẹẹẹdogun ati mẹrindinlogun ti wọn n ṣedanwo igbaniwọle.

“A o wa nnkan ṣe si ọrọ yii, nitori awọn ọmọ yẹn ti kere ju ki wọn gbọ nnkan ti wọn n kọ ọmọ ni fasiti ye lọ. Ti wọn ba ti kere ju lọjọ ori, wọn ko ni i ri wọn dari daadaa. Mo lero pe ara nnkan ta a n ri lawọn ileewe fasiti wa lonii niyẹn”.

Bakan naa ni Mamman dabaa pe awọn yoo pese eto iṣẹ ọwọ kikọ fawọn ti ko ba lanfaani lati wọle sileewe giga. O ni lati ileewe alakọọbẹrẹ nileeṣẹ awọn yoo ti bẹrẹ eto iṣẹ ọwọ ni kikọ fawọn akẹkọọ bayii.

“Lakootan, ida ogun pere ni wọn le gba wọle si fasiti, ileewe gbogbo-niṣe (Polytechnic) ati ileewe ti wọn ti n kọṣẹ olukọ (College of Education).

Nibo waa ni ida ọgọrin yooku yoo lọ? Idi niyi tọrọ iṣẹ ọwọ ni kikọ fi ṣe pataki.

Akẹkọọ yoowu ti ko ba ribi wọle iwe giga gbọdọ ni igbesi aye to dara lẹyin ikẹkọọ jade ni pamari ati girama, ọna abayọ kan ṣoṣo si eyi si ni iṣẹ ọwọ kikọ”.

Fabian Benjamin, ti i ṣe agbẹnusọ ajọ to n ṣeto idanwo aṣewọle sileewe giga, JAMB, naa kin ọrọ minisita yii lẹyin, o ni ọdun mejidinlogun tọmọ yoo wọle ẹkọ yii wa ni ibamu pẹlu eto ẹkọ ọlọdun mẹfa, mẹta, mẹta ati mẹrin, ti wọn n pe ni 6-3-3-4.

 

Leave a Reply