Florence Babaṣọla
Ọmọkunrin kan, Ismaial Lawal, lo ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu Ileefẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lori ẹsun pe o dana sun ọkada ẹnikan to fura si pe o n yan ọrẹbinrin rẹ lale.
Agbefọba to gbe Lawal wa si kootu, Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi, ṣalaye pe ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni olujẹjọ huwa naa.
Ṣe ni olujẹjọ, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, lọ si ile Lawal Abdullahi ni Adejokun Compound, Ilarẹ, ni nnkan bii aago meji kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn, lọganjọ oru.
Osanyintuyi fi kun ọrọ rẹ pe ṣe ni olujẹjọ jalẹkun wọle naa, to si dana sun ọkada Bajaj Boxer meji alawọ pupa to ba nibẹ.
O ni iwa to hu ọhun nijiya labẹ abala okoolenirinwo o din mẹsan-an ati ojilenirinwo o le mẹrin ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni agbẹjọro rẹ, Okon Wonder, bẹbẹ fun beeli rẹ pẹlu irọrun, o ni ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.
Onidaajọ A. A. Ayẹni fun un ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro meji ni iye kan naa.
O ni oniduuro naa gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu, o si gbọdọ ni iṣẹ gidi lọwọ pẹlu ẹri owo-ori ọlọdun mẹta.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ogunjọ, oṣu keje, ọdun yii.