Niluu Ẹdẹ, awọn eeyan ti n da ẹru ti wọn ji ko pada fun ijọba

Aderounmu Kazeem

Laduugbo kan ti wọn pe ni Unit One l’Owode, niluu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun, awọn eeyan ti n da ẹru ti wọn ji ko lasiko rogbodiyan to bẹ silẹ lọsẹ to kọja pada o.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe ni kete ti ijọba ti kede pe ki awọn eeyan ilu da awọn ohun ti wọn ba ji ko pada laarin ọjọ mẹta, lawọn eeyan ti gbọ ipe yii, ti awọn kan si ti n ru tiwọn pada bayii.

Ohun ti ijọba Ọṣun sọ ni pe, ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pẹlu awọn ohun ti ijọba n wa yii, oju ẹlẹwọn loun yoo fi wo wọn, bẹẹ nirufẹ ẹni bẹẹ yoo faṣọ penpe roko ọba.

2 thoughts on “Niluu Ẹdẹ, awọn eeyan ti n da ẹru ti wọn ji ko pada fun ijọba

Leave a Reply