Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lasiko tawọn eeyan n mura ọdun tuntun l’Ọjọbọ ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2020, niṣe ni mọto ayọkẹlẹ Venza kan to n sare buruku bọ lati Lafẹnwa, l’Abẹokuta, lọọ kọlu ọlọkada to n lọ jẹẹjẹ ẹ. Ọkunrin naa rebọ lati ori ọkada yii, o fori gbalẹ, o si dagbere faye loju ẹsẹ.
Awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn lo ṣalaye pe Lafẹnwa ni awakọ naa ti n bọ, ibẹ naa si ni ọlọkada ti nọmba maṣinni ẹ jẹ KNN 389 VT, ti n bọ pẹlu.
Wọn ni awọn mejeeji ti de agbegbe Rounder, iwaju ileepo kan to wa nibẹ ni wọn de ti awakọ to n wa Venza fi kọlu ọlọkada yii lẹgbẹẹ. Ẹsẹkẹsẹ ni ọlọkada rebọ, nitori ikọlu naa lagbara pupọ pẹlu bo ṣe jẹ ere buruku ni dẹrẹba n sa.
Bi ọlọkada ṣe re bọ lori alupupu lo fi ori gbalẹ, iku lo si ja si fun un lọsan-an ọjọ naa.
Ko tiẹ too di pe awọn TRACE to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ yii debẹ lawọn eeyan ti fẹẹ da sẹria fun awakọ naa, ṣugbọn o raye sa mọ wọn lọwọ. Wọn fẹẹ dana sun mọto Venza ti nọmba ẹ jẹ GGE 871 GN naa, ṣugbọn awọn agbofinro de wọn si gbe mọto naa lọ.
Yatọ si ọlọkada to ku lọdun kọla yii, ẹnikan naa tun farapa ninu ikọlu ọhun.
Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni awakọ Venza lo n sare to lọọ kọlu ẹni ẹlẹni to n ṣiṣẹ aje rẹ lọ jẹẹjẹ. O ni teṣan ọlọpaa Lafẹnwa ni mọto ayọkẹlẹ naa wa bayii,awọn si ti gbe oku ọlọkada lọ si mọṣuari ọsibitu Ijaye, l’Abẹokuta.