Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọmọ ogun ọdun ni Samuel Ogungbe, igbo lo n ta ni Mowe, ohun ti wọn tori ẹ mu un lọsẹ to kọja yii niyẹn ti wọn si mu un wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta . Eyi ni alaye ti ọmọ naa ṣe fun AKEDE AGBAYE.
“Igbo ni mo n ta ni Mowe, ọlọpaa waa mu mi lọjọ Mọnde to kọja, nitori wọn ba mi nibi ti mo ti n ta igbo ti wọn dẹ tun ba igbo lọwọ mi.
“Ọndirẹdi naira(N100) ni mo n ta igbo mi, mo dẹ maa n ri ẹgbẹrun marun-un naira lojumọ, mo maa n dajọ ẹgbẹrun kan tabi meji nigba mi-in ninu owo ti mo n ri. Ko dẹ ki i ṣe pe mo fẹẹ maa tagbo bẹẹ naa o, owo firidọọmu ni mo n wa, nitori mo kọṣẹ bi wọn ṣe n tun ọkada ṣe. Mi o fẹe jale lo jẹ ki n maa lọọ tagbo yẹn, oṣu keji ti mo ti n ta a ree ti mo dẹ n ri nnkan to daa ṣe nibẹ.
“Mo ti f’ọmọ loyun bẹ ẹ ṣe n wo mi yii, ọmọ ẹlẹ ti mo n fẹ ti loyun. Mo nigbagbọ pe mo maa jade nibi, ẹ ba mi bẹ awọn ọlọpaa ki wọn tu mi silẹ, ki n lọ sile lọọ ba iyawo mi’’
Nipa irun buruku to ṣe sori, Samuel to ni ọmọ Ibadan loun, ṣalaye pe irun ọdun loun ṣe. O ni nitori ọdun wa nita loun ṣe kun irun kolokolo toun ṣe sori naa lọda pupa, nitori aṣa to wa nita bayii niyẹn.
Njẹ nibo lo ti n ra igbo to n ta, Samuel sọ pe ẹnikan to n jẹ Joseph lo maa n gbe igbo naa foun. O ni Abẹokuta ni Joseph ti maa n waa ra igbo naa, ati pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.
Samuel sọ pe, ‘’ Nigba ti Joseph gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu mi lo gbe bọdi ẹ, o sa lọ ni tiẹ ni. Wọn o ti i ri i titi di bayii’’
Awọn ọlọpaa ti ni afi ko de kootu laipẹ, nitori oun funra rẹ naa loun mọ pe eewọ ni igbo tita ati mimu ninu ofin ilẹ yii.