Monisọla Saka
Afurasi ọdaran kan, Akpan Okon Akpan, to n ta epo bẹntiroolu inu galọọnu lẹsẹ titi, yoo ro ẹjọ, ẹnu rẹ yoo si fẹrẹ bo lati jajabọ lori bi wọn ko ṣe ni i fiya jẹ ẹ pẹlu bo ṣe fi ibunu dana sun ọrẹ rẹ, Junior Ime Philip, nitori ṣaaja ti wọn fi n ṣaaji foonu lasan.
Nigba to n ṣalaye ohun to fa a to fi dana sun eeyan nitori ariyanjiyan to waye latari ṣaaja, o ni, “Ki i ṣe pe mo mọ ọmọkunrin yẹn ri tẹlẹ, o kan sare wọ ṣọọbu mi lọjọ yẹn pe oun n wa ẹni kan to gba ṣaaja oun ni, mo si da a lohun pe ko siru eeyan bẹẹ ninu ṣọọbu mi. Lojiji lo binu fa igo yọ, to bẹrẹ ija pẹlu mi, bi emi ati ẹ ṣe bẹrẹ si i ja niyẹn.
‘‘Bẹntiroolu ti mo n ta ni mo rọ le e lori, amọ ni tododo, mi o mọ nnkan ti mo n ṣe ni gbogbo igba yẹn, afigba ti mo ri i to n jona, tawọn eeyan pe jọ sibẹ. A gbiyanju gbogbo agbara wa lati pa ina naa, ṣugbọn ẹpa o boro mọ nitori nigba ti wọn fi maa gbe e de ọsibitu, ko pẹ pupọ to fi dakẹ”.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Akwa-Ibom, Ọlatoye Durosinmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lasiko ti wọn n foju awọn afurasi han lẹyin tọwọ ti ba Akpan, ṣalaye pe afurasi yii kọkọ da epo bẹtiroolu si ọrẹ ẹ lara lasiko ti wọn jọ n ṣe fa-n-fa-a, ki wọn si too boju wo boju ri, o ti ju ina si i lara, o si fi i silẹ ninu inira b’ọmọkunrin naa ṣe n japoro titi to fi ku.
O ni, ” Ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ, awọn oṣiṣẹ wa lẹka ti wọn ti n ri si ẹsun ipaniyan, SCID Uyo, lọọ fi panpẹ ofin gbe ọkunrin kan to n jẹ Akpan Okon Akpan, to fibinu da bẹntiroolu le Junior Ime Philip, ti i ṣe aburo Alagba Emmanuel lori, to si tun dana si i lojiji, eyi to ṣokunfa iku oloogbe yii nitori ṣaaja”.
Ṣaa, afurasi ṣi wa lakolo awọn ọlọpaa, nigba ti iwadii ṣi n tẹsiwaju.