Faith Adebọla, Eko
Ahamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lawọn baale ile mẹta kan ti n ṣalaye ohun ti wọn ri lọbẹ ti wọn fi waro ọwọ bayii latari ẹsun pe wọn lọwọ si iku afurasi adigunjale kan ti wọn lu lalubolẹ titi tonitọhun fi ku l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, lagbegbe Ikọtun, nipinlẹ Eko.
Orukọ awọn mẹtẹẹta ti wọn fẹsun iṣikapaayan kan ni Sakariyau Biliaminu, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin (66), Alagba John Adeyẹmi, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin (77) ati Gabriel Ajayi, ẹni ọdun marundinlọgọta, wọn nipo olori ilu lawọn mẹtẹẹta wa n’Ikọtun.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, afurasi adigunjale kan ni wọn lo gba oke aja wọle Abilekọ Adeyẹmi, to n gbe Ojule keji, ibudokọ Asalu, nitosi ọna to lọ si Abaranjẹ, n’Ikọtun, lọjọ Wẹsidee ọhun.
ALAROYE gbọ pe nibi ti ọdaran naa ti n ko ẹru ẹlẹru lọwọ ni onile wọle ba a lojiji, niyẹn ba figbe ta pe ki araadugbo gba oun o, ole ti n ko oun lẹru.
Koloju too ṣẹ ẹ, wọn ni jagunlabi ti bẹ sigboro, o fẹẹ sa lọ, lawọn ọdọ to wa lagbegbe naa ba ya bo o, wọn si lu u nilukilu, wọn ni igi ati akufọ bulọọku ni wọn n la mọ ọn, ẹyin eyi ni wọn ni wọn wọ ọ lọ sọdọ awọn olori kọminiti, n lawọn baba agbalagba mẹta yii ba ni kawọn ọdọ naa fa a lọ sagọọ ọlọpaa.
A gbọ pe kaka kawọn ọdọ mu un lọ si tọlọpaa, niṣe ni wọn tubọ fibinu din dundu iya fun ọdaran ọhun, ẹnu sẹria ọhun ni wọn lo dakẹ si, lawọn ọdọ ba tuka, onikaluku ba ẹsẹ rẹ sọrọ loju-ẹsẹ.
Awọn ọlọpaa ni wọn waa gbe oku ọkunrin naa lọ, ni wọn ba bẹrẹ si i fimu finlẹ, wọn lolobo si ta wọn pe awọn olori ilu mẹtẹẹta naa ni alaye lati ṣe fawọn, eyi lo sọ wọn dero Panti, ni Yaba, lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, gẹgẹ bii aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu pa.
Odumosu sọ ninu atẹjade kan pe ko tọna fẹnikẹni lati fọwọ ara rẹ da sẹria fun afurasi ọdaran kankan, o niwa ọdaran ni fẹnikan lati ṣe bẹẹ, ẹsun nla si ni pẹlu tọrọ ọhun ba lọọ ni ti iku ninu.