Ọwọ tẹ awọn to n ta ẹya ara eeyan n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, marun-un ninu awọn to n ta ẹya ara eeyan nipinlẹ Ọyọ lọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii. Ẹran eeyan lawọn fi n ṣe kara-kata ni tiwọn, ẹgbẹrun mẹwaa naira ni wọn si n ta odidi ọkan eeyan fawọn to ba fẹẹ fi i ṣoogun owo.

L’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ wọn to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan.

Ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji (35) kan to n jẹ Jimoh Sabiku lo da bii agbodegba fun awọn mẹrin yooku. Orukọ awọn yooku ni Adeṣọla David, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24); Bello Waheed, ẹni ọdun marundinlaaadọta (45); Habeeb Musa, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34) ati baba ẹni ọdun mọkanlelaaadọta (51) kan Musibau Aroju.

CP Onadeko ṣalaye pe “Lọjọ kan bayii, ninu oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ni Jimoh Sabiku lọọ ba Musibaudeen Aroju pe oun fẹẹ ra ọkan eeyan lati fi ṣoogun owo. Ṣugbọn iyẹn da a lohun pe oun kọ loun n ta a, ṣugbọn oun le mu un dọdọ oniṣowo ẹya ara eeyan naa ti n jẹ AafaaTaofeek, ti wọn tun n pe ni Kari-ile.

“Lọdọ Aafaa Kari-Ile to fi ilu Ṣaki ṣebugbe yii naa ni wọn ti ri abami ẹran ọhun ra lẹgbẹrun mẹwaa naira lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii.

“Jimoh waa mu ẹya ara eeyan yii lọọ fun ọkunrin kan to n jẹ Adeṣọla David, o ni ko ba oun fun Bello Waheed niluu Isẹyin, ni ipinlẹ Ọyọ, kan naa. Ṣugbọn David ko ti i mu kinni naa de ọdọ Waheed ti ọwọ palaba gbogbo wọn fi segi.”

Nigba to n sọrọ lori bọwọ se tẹ wọn, ọga agba ọlọpaa ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ kokandinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii, lawọn ọlọpaa da David ati ọkunrin kan to n jẹ Habib Muda duro lori okada kan ti nọmba rẹ jẹ AYE 125 QE  (ỌYỌ) lọna titi ẹsipirẹẹsi to ti Igbẹti lọ siluu Igboho, ti wọn ko si ri alaye gidi kankan ṣe nigba ti awọn agbofinro tu ẹru ọwọ wọn, ti wọn si ba ọkan eeyan ninu ọra ti wọn gbe lọwọ.

CP Ọnadeko ni bakan lawọn eeyan oun ka eegun oku eeyan mọ ọkunrin kan naa to n jẹ Azeez Akinolu Wasiu lọwọ laduugbo Alakukọ, niluu Ibadan.

Njẹ nibo lo ti ri eegun ara oku eeyan, ọkunrin oniṣegun yii dahun pe oun lọọ hu u jade ninu saaree kan niboji oku to wa laduuugbo Elegbo, niluu Ọyọ ni.

Ati eegun ara eeyan yii, ati ọkan eeyan ti wọn gba lọwọ awọn afurasi ọdaran wọnyi ti wa lakata awọn ọlọpaa bayii nigba ti awọn afurasi ọdaran naa wa ni Iyaganku, n’Ibadan, iyẹn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti wọn ti n ṣewadii ẹsun ọdaran.

CP Onadeko seleri pe ni kete ti iwadii awọn ba ti pari loun yoo gbe awọn afurasi ọdaran naa lọ si kootu.

 

Leave a Reply